Russia 2018: Gernot Rohr kéde orúkọ agbábọ́ọ̀lù 30

Ikọ agbabọọlu Super Eagles Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ikọ agbabọọlu Super Eagles n ya fọto saaju ifẹsẹwọnsẹ kan

Akọnimọgba ikọ Super Eagles, Gernot Rohr, ti kede awọn agbabọọlu ọgbọn ti wọn o mu lara wọn, lati ṣoju orilẹede Naijiria ninu ife ẹyẹ agbaye ti yoo waye ni osu kẹfa ọdun yii.

Balogun ikọ Super Eagles Mikel Obi, Ogenyi Onazi, Wilfred Ndidi ati Oghenekaro Etebo wa lara awọn agbabọọlu aarin gbungbun ti wọn wa lori iwe naa.

Oju opo Twiitter ajo to'n risi ere boolu lorileede Naijiria ni wọn fi ikede naa si.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Awọn asọle to wa lori iwe orukọ naa ni Ikechukwu Ezenwa, Daniel Akpeyi, Francis Uzoho ati Dele Ajiboye.

Awọn ololufẹ ere bọọlu l'orilẹede Nàìjírìa ti foju sọna fun iwe orukọ tipẹ ko to jade loni.