Niger Tornadoes: Àdánù ńlá ni iku Hussaini Isiah

Hussein Isiah Image copyright Niger Tornadoes
Àkọlé àwòrán Ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ ajé ni ọlọ́jọ́ dé fún Hussein Isiah ní ìlú Minna

Ajalu nla lo ṣẹlẹ lagbo ere bọọlu liigi orilẹede Naijiria pẹlu iku agbabọọlu Niger tornadoes, Hussaini Isiah, ni irọlẹ ọjọ aje.

Gẹgẹ bi iroyin ṣe sọ, iku wọle ti Hussaini Isiah, nigba ti ọlọkada kan kọlu u ni ilu Minna.

Hussaini Isiah kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ Niger Tornadoes pẹlu kwara United ni ọjọ aiku, ti wọn tilẹ tun yan an gẹgẹbii agbabọọlu to pegede ju lọ ninu ifẹsẹwọnsẹ naa ti wọn gba ni papa iṣere Kotangora nilu Minna.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAlukoro Super Eagles: Ọjọ́ kẹrin, osù kẹfà ni orúkọ yóò jáde

Iku Hussaini waye ni oṣu diẹ lẹyin ti gbaju-gbaja agbabọọlu Eyimba nigbakan ri, Chinedu Udoji kagbako iku ninu iṣẹlẹ ijamba ọkọ kan.

Ọpọ awọn ẹgbẹ agbabọọlu lorilẹede Naijiria ni wọn ti ba ẹgbẹ agbabọọlu Niger tornadoes ati ẹbi Hussaini Isiah kẹdun.

Ninu ọrọ ti wọn fi sita lori ikanni twitter, ajọ ere bọọlu lorilẹede Naijiria, NFF ni ibanujẹ nla ni iku naa jẹ.

Image copyright Niger Tornadoes
Àkọlé àwòrán Hussein Isiah kàgbákò ikú òjijì nígbà tí alúpùpù kan kọ lùú

Ninu ọrọ tirẹ Gomina ipinlẹ Niger, Abubakar Sani-Bello, ṣapejuwe iku agbabọọlu naa gẹgẹ bii adanu nla fun ipinlẹ Niger ati awujọ wa lapapọ.

"Mo ṣi wo o lọjọ aiku to gba bọọlu fun ikọ wa ni papa iṣere Kotangora. Agbabọọlu to kun oju iwọn ni, iyalẹnu ni iku rẹ si jẹ fun wa."

Bakanna lori ikanni Twitter rẹ, ẹgbẹ agbabọọlu Niger Tornadoes ṣe apejuwe agbabọọlu naa gẹgẹ bii olufọkansin ati oniwa irẹlẹ.

"Adanu nla ni fun wa ati fun agbo ere bọọlu lorilẹede Naijiria."