Australia: Yóò da kí eléré ìdárayá tó sálọ tètè padà sílé

Petit Minkoumba Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Agbérin ọmọ ilẹ̀ Cameroon Petit Minkoumba jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ orílẹ̀èdè náà tó sálọ ní Australia

Awọn elere idaraya mẹwa ati olukọ kan lati ilẹ Afrika, ti wọn sa lọ lakoko idije Commonwealth Games ni orilẹede Australia, ni wọn ti fẹ le pada bayi.

Mẹjọ ninu awọn elere naa lo wa lati orilẹede Cameroon, meji ninu wọn jẹ ọmọ ilẹ Uganda, ti ẹnikan yooku si wa lati Rwanda.

Minisita ọrọ abẹle nilẹ naa, Peter Dutton sọ pe, awọn èèyàn mọkanla naa yoo di arufin nigbati ọjọ ba lọ lori iwe asẹ iwọlu wọn l'aago mejila oru alẹ ọjọ iṣẹgun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Awọn elere idaraya lati orilẹede Cameroon naa, ni marun un ninu wọn jẹ akanṣẹ, ti mẹta si jẹ agbérin.

Image copyright ANDREJ ISAKOVIC/GETTY
Àkọlé àwòrán Kò sí ikọ eléré ìdárayá ọmọ orílẹ̀èdè Naijiria ni Rio Olympics tó sálọ

Wọn ko ida kan ninu idamẹta awọn elere idaraya to ṣoju Cameroon, ninu idije Commonwealth Games ni Australia.

Ẹwẹ, awọn ọmọ ilẹ Cameroon meje ni wọn sa lọ, nigbati wọn wa ni ilu London fun idije Olympics ni ọdun 2012.