Ìpànìyàn Benue: Ìsìnkú Fada àtàwọ́n ọmọ ìjọ yóò wáyé l'ọ́jọ́ Ìṣégun

Pósí àwọn èèyàn tí darandaran ti pa sẹ́yìn Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Àìmọye ìgbà ni darandaran ti rán ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ èèyàn ìpínlẹ̀ Benue sí ọ̀run ọ̀sán gangan

Ikọ aṣoju Poopu ati aadọta bisọbu ni yoo wa nibi isinku àwọn Fada méjì pẹ̀lú ọmọ ìjọ mẹ́tàlá ti Ìjọ Aguda, ipinlẹ Benue.

Awọn ọmọlẹhin Kristi yii padanu ẹmi wọn lat'ọwọ awọn darandaran ni Ipinlẹ Benue l'ọjọ iṣẹgun.

Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe awọn ọmọ ijọ Aguda kaakiri orilẹede Naijira yoo ṣe iṣọ oru lalẹ ọjọ naa.

Agbẹnusọ fun ijọ Aguda nilu Makurdi, Fada Moses Iorapuu sọọ di mimọ pe awọn bisọbu ni wọn mu ọjọ isinku naa nibi ipade wọn nilu Rome.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O fikun ọrọ rẹ pe ọjọ naa tun ṣe pẹki pẹlu ayẹyẹ ọjọ ti Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Benue fọwọ si ofin to tako kiko ẹran jako ni gbangba ni Ipinlẹ naa.

Iorapuu sọ pe awọn bisọbu n ṣe'pade lọwọ nigbati ikọlu awọn darandaran naa ṣẹlẹ ni ipinlẹ naa.