Nadal fàgbà han Zverev láti gba ife ẹ̀yẹ Italian Open

Rafael Nadal

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Rafael Nadal ti gba ìdíje Italian Open lẹ́mẹ̀ẹ́jọ

Agbaọjẹ elere bọọlu tẹniisi Rafael Nadal ti wa ni ipo kinni pada l'agbaye lẹyin igbati o jawe olubori ninu idile Italian Open fun igba kẹjọ.

Nadal lo kọkọ ni ami ayo kan ki alatako rẹ Alexander Zverev to da pada.

Ṣugbọn Nadal to jẹ ọmọ bibi orilẹede Spain fagba han Zverev pẹlu amin ayo miran to si pegede ninu ifẹsẹwọnsẹ naa pẹlu ami ayo meji s'ọkan.

Nadal nikan lo ti gba ife ẹyẹ Italian Open ju gbogbo akẹgbẹ rẹ lọ

Roger Federer lo kọkọ wa ni ipo akọkọ ninu gbogbo awọn elere bọọlu tẹniisi lagbaye tẹlẹ nigbati Nadal fidi rẹmi ninu idije Madrid Open l'ọṣẹ to kọja.

Ṣugbọn Nadal ni yoo jẹ agbaọjẹ elere bọọlu tẹniisi ninu idije French Open ni orilẹede Faranse.