'Mi ò ní gbàgbé yín láíláí', Iniesta ṣeleri fun Barcelona

Iniesta pẹ̀lú àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Iniesta gbá bọ́ọ̀lù fún ikọ̀ Barcelona fún ọdún méjìlélógún

Agba-ọjẹ agbabọọlu Andres Iniesta pẹlu omije loju ṣe ileri pe oun ko ni gbagbe ẹgbẹ agbabọọlu Barcelona ati awọn ololufẹ rẹ lailai.

Iniesta ṣoju ikọ agbabọọlu naa fun igba ikẹyin lọjọ Aiku, nigbati Barcelona koju Real Sociedad lẹyin igbati ti o ti wa nibẹ fun ọdun mejilelogun.

Barcelona fagban han ẹgbẹ agbabọọlu Real Sociedad pẹlu ami ayo kan ṣ'odo ninu ifẹsẹwọnsẹ La Liga naa.

Agbabọọlu aarin gbungbun Phillipe Coutinho lo gba ayo naa wọle ni iṣẹju mẹtadinlọgọta.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Iniesta wá lára àwọn agbábọ́ọ̀lù tí àwọn olólùfẹ́ Barcelona fẹ́ràn jù

Lẹyin naa ni wọn gbe ife ẹyẹ La Liga fun ẹgbẹ agbabọọlu Barcelona fun saa yii.

Iniesta ti sọ tẹlẹ pe oun yoo fi adagba oun rọ pẹlu ikọ Barcelona nipari saa yii.