Arsenal: Cazorla jẹ́ agbábọ́ọ̀lù tí irú rẹ̀ ṣ'ọ̀wọ́n

Santi Cazorla

Oríṣun àwòrán, Arsenal

Àkọlé àwòrán,

Lẹ́yìn ọdún mẹ́fà, Santi Cazorla dágbére fún Arsenal

Gbajugbaja agbabọọlu Arsenal, Santi Carzola, ti fi ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal silẹ.

Cazorla n fi Arsenal silẹ lẹyin ọdun mẹfa to lò nibẹ.

Ọgọsan ifẹsẹwọnsẹ ni Cazorla gba fun Arsenal pẹlu goolu mọkandinlọgbọn.

Ninu ọrọ rẹ, Ọga agba ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal, Ivan Gazidis, ni, "Ọkan lara awọn agbabọọlu ti mo fẹran julọ ni Santi jẹ. Ẹbun rẹ lati lo ẹsẹ mejeeji fi gba bọọlu àti bi o ṣe tete maa n ronu si jẹ diẹ̀ lara awọn ohun to mu ki o jafafa. Idunnu lo fi maa n gba bọọlu, ni eyi ti ko wọpọ rara. Adura wa ni pe ọjọ iwaju yoo san an. Bakan naa ni a dupẹ lọwọ rẹ fun ipa ribiribi to ko ninu itẹsiwaju ẹgbẹ agbabọọlu wa."

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ninu ọrọ ti oun pẹlu sọ ninu fidio kan to fi si ori ikanni twitter ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal, Santi Cazorla ni 'ibanujẹ ọkan lo jẹ fun oun lati fi ẹgbẹ naa silẹ' ṣugbọn oun ko lee gbagbe Arsenal laelae".

Amọ ṣa, ifaraṣeṣe rẹ lọpọ igba ko jẹ ki o da bi ẹdun, kó rọ̀ bi òwè fun Arsenal lati nnkan bii ọdun kan abọ sẹyin, eyi si ni ọpọ n wo gẹgẹ bii idi ti o fi n fẹyinti ni Arsenal.