Emery fẹ́ rọ́pò Wenger gẹ́gẹ́ bí akọ́nimọ̀ọ́gbá Arsenal

Akọ́nimọ̀ọ́gbá Unai Emery

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Unai Emery gba ife ẹ̀yẹ mẹ́ta ní sáà méjì tó fi ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ikò agbábọ́ọọ̀lù Paris St-Germain

Ikọ Arsenal ti fẹ gba akọnimọgba Unai Emery lati rọpo akọnimọọgba Arsene Wenger to lọ.

Mikel Arteta to jẹ igbakeji akọnimọọgba ni ikọ Manchester City lo da bi pe o ma rọpo Wenger tẹlẹ.

Ṣugbọn Emery lo fakọyọ julọ ninu ifọrọwanilẹnuwo ti wọn ṣe fun awọn to kowe fun ipo akọnimọọgba ikọ Arsenal.

Emery to jẹ ọmọbibi orilẹede Spain fi ẹgbẹ agbabọọlu Paris St-Germain to n dari silẹ l'opin saa yii.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Unai Emery ti ṣiṣẹ́ ní Sevilla àti PSG tẹ́lẹ̀ rí

Akọnimọọgba Emery to jẹ ọmọ ọdun mẹrindinlaadọta gba ifẹ ẹyẹ mẹta pẹlu ikọ PSG nigba to wa pẹlu wọn.

Emery ti figba ri jẹ akọnimọgba Sevilla ni orilẹede Spain nibi ti o ti gba ife ẹyẹ Europa lẹmẹta lera wọn laarin ọdun 2014 si ọdun 2016.