Super Eagles ṣetán láti kojú Atletico Madrid

Aworan Fernando Torres

Oríṣun àwòrán, @atletienglish

Àkọlé àwòrán,

Atletico Madrid ṣẹṣẹ gbà ife ẹ̀yẹ Europa ọdún 2017 ní

Papa isere Godswill Akpabio ní ìlú Uyo tí n sọ putuputu fún ifẹsẹwọnsẹ láàrin ìkọ agbaboolu Super Eagles orílèèdè Nàìjíríà àti ẹgbẹ́ agbaboolu Atletico Madrid.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ifẹsẹwọnsẹ náà yóò wáyé laṣalẹ òní.

Lójú òpó Twitter ìkọ Super Eagles, nṣe ní wọn fí àwòrán àwọn agbábọ́ọ̀lù Nàìjíríà han bi wọn ti ṣe n ṣé igbaradi.

Oríṣun àwòrán, @NGSuperEagles

Àkọlé àwòrán,

Salisu Yusuf ní akọni ti o'n darí àwọn agbaboolu Nàìjíríà fún ifẹsẹwọnsẹ náà

Àwọn agbábọ́ọ̀lù ìsọ̀rí keji Super Eagles ni yóò kópa nínú ìdíje náà ti a si rí nínú wọn ti o n gbà bọ́ọ̀lù fún ẹgbẹ agbábọ́ọ̀lù towa nile àti lẹyìn òdì.

Akoni-moogba ìkọ ìsòrí keji Super Eagles Salisu Yusuf pé agbaboolu mẹ́tàlélógún fún ifẹsẹwọnsẹ náà.

Lára wọn láti rí atamatase ẹgbẹ agbaboolu Plateau United, Tosin Omoyele ati agbaboolu Katsina United Destiny Ashadi

Oríṣun àwòrán, @NGSuperEagles

Àkọlé àwòrán,

Anfààní rẹ fún àwọn agbaboolu ìsòrí keji láti fi ará wọn hàn sí akoni-moogba Genort Rohr

Bákannáà ni àwọn ọmọ ẹgbẹ agbaboolu Atletico Madrid fi ìkíni síta lójú òpó Twitter wọn ní kété tí wọ́n gúnlè sí Nàìjíríà.