Ìdíje ọlọ́rẹ̀sọ́rẹ̀: Super Eagles jákulẹ̀ pẹ̀lú ayò méjì sí mẹ́ta

Awọn agbabọọlu Athletico n dunnu
Àkọlé àwòrán,

Àwọn ìpín kejì Super Eagles tí wọ́n ń gbá bọ́ọ̀lù jẹun lórílẹ̀èdè Nàìjíríà ni wọ́n kópa nínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ náà

Ami ayo mẹta ni ikọ ẹgbẹ agbabọọlu Athletico Madrid fi gbẹyẹ mọ ikọ Super Eagles ti orilẹede naijiria lọwọ, ni alẹ ọjọ iṣẹgun nibi ifẹsẹwọnsẹ ọlọrẹsọrẹ to waye ni papa isere Godswill Akpabio ní ìlú Uyo nipinlẹ Akwa Ibom.

Ami ayo meji pere si ni Super Eagles ti orilẹede Naijiria ni.

Ifẹsẹwọnsẹ naa jẹ idije ife ẹyẹ Gotv cup, eyi ti wọn fi n ṣe igbaradi fun ikọ keji Super Eagles ti wọn jẹ agbabọọlu ti wọn n gba bọọlu jẹun lorilẹede naijiria.

Ọmi alayo kọọkan ni wọn fi pari abala akọkọ ifẹsẹwọnsẹ naa, lẹyin ti Kelechi Nwakali ti kọkọ gba ayo wọle fun orilẹede Naijiria, ti Angel Correa si daa pada fun ikọ Athletico nigbati ifẹsẹwọnsẹ naa wọ iṣẹju mejilelọgbọn.

Fernando Torres to wole ni abala keji ifẹwọnsẹ naa, lo yi oju ayo pada fun Athletico lẹyin to fi ori gbe ayo kan wọle, eleyi ti ipa aṣọle orilẹede naijiria ko si ka.

Àkọlé àwòrán,

Iṣẹju marun pere lo ku ki ifẹsẹwọnsẹ naa o pari, ti agbabọlu Athletico, Borja fi gba goolu kẹta wọle

Amọ ṣa, ki a to ṣẹju pẹ ni Usman Mohammed tun daa pada fun ikọ Super Eagles.

Iṣẹju marun pere lo ku ki ifẹsẹwọnsẹ naa o pari, ti agbabọlu Athletico, Borja fi gba goolu kẹta wọle.

Awọn agbabọọlu Naijiria to kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ naa ni Thomas, Musa Muhammed, Ebube Duru, Olamilekan Adeleye, Chinedu Ajanah, Emem Eduok, Alhassan Ibrahim, Chidiebere Nwakali, Kelechi Nwakali, Ekundayo Ojo, Kadiri Samad.

Oblak, Juanfran, Rafa Muñoz, Montero, Sergi, Thomas, Toni Moya, Olabe, Mikel, Correa ati Gameiro lo kopa fun ikọ Athletico.