Àwọn agbòfinro Ghana gbé Kwesi Nyantakyi

Kwesi Nyantakyi Image copyright FIFA.COM
Àkọlé àwòrán Wọ́n fi ẹ̀sùn ìwà ìbàjẹ́ kan alága àjọ tó n mójútó bọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá ní Ghana.

Ọwọ àwọn ọlọ́pàá ọtẹlẹmuyẹ lorílè-èdè Ghana ti tẹ alága àjọ tó n mójú tó bọọlu lorílè-èdè náà.

Wọn gbé ni kété to balẹ̀ si pápáko òfurufú àgbáyé Kotoka láti irinajo tó ṣe sí orílèèdè Morocco.

Ìròyìn tó tẹwa lọwọ sọ pé àwọn oṣiṣẹ ileese ọtẹlẹmuyẹ àpapọ ló kókó gbé ti wọn sì fa le àwọn agbofinro lọwọ.

Ṣáájú ni Ààrẹ orílẹ̀èdè Ghana, Nana Akufo-Addo ti pàṣẹ pé kí wọ́n fi pańpẹ́ òfin mú alága àjọ tó n mójútó bọ́ọ̀lù aláfẹsẹ̀gbá l'órílẹ̀èdè nàá.

Kwesi Nyantakyi, tó tún jẹ́ igbákejì ààrẹ àjọ tó n ṣe kòkáàrí bọ́ọ̀lù aláfẹsẹ̀gbá ní ilẹ̀ Afrika, ni wọ́n fi ẹ̀sùn kàn pé, ó hu ìwà jẹgúdújẹrá.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Kwesi Nyantakyi ti wà ní ipò alága nàá láti ọdún 2005.

Ẹ̀wẹ̀ àjọ tó ń rí sí erébóòlù lágbàáyé, Fifa ti sọ fún ilé iṣẹ BBC pé àwọn n fi ọkàn bá ọrọ náà ló.

Wọn ní àwọn ṣì n ''ṣé iwadi'' torí náà awọn kò ti le sọrọ nípa ìṣẹlẹ òun.

Ìròyìn fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé, Nyantakyi n lo orúkọ Ààrẹ Akufo-Addo tó fi mọ́ ti igbákejì rẹ̀, àti àwọn òṣìṣẹ́ àgbà lẹ́nu iṣẹ́ ọba, láti fi fa ojú àwọn olùdókòwò mọ́ra, láti fi gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ mílíọ́nù Dọ́là lọ́wọ́ wọn.

Wọ́n fi ẹ̀sùn kàn án wí pé, ó ní "àtẹ́lẹwọ́ òun ni Ààrẹ nàá wà."