Unai Emery di akọnimọọgba Arsenal

Aworan Unai Emery ati Ivan Gasidis Image copyright PA
Àkọlé àwòrán Unai Emery nibi afihan re pelu asaaju Egbe Arsenal Ivan Gasidis

Unai Emery ni akọni moogba tuntun fun ẹgbẹ́ agbaboolu Arsenal.

Ẹgbẹ náà fi ìkéde iyansipo rẹ ati ìkínni káàbọ̀ sójú òpó Twitter wọn.

Emery n darapo mọ ẹgbẹ Arsenal láti PSG níbi tí ọ ti gbà ìfé ẹyẹ liigi pẹlú wọn.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Unai Emery ni akonimoogba akọkọ ti Arsenal gba lẹyin ọdun mejilelogun

Bákannáà ni o tí gbà ife ẹyẹ Europa league pẹlú Sevilla ni ẹẹmẹta otooto.

Emery ni inú oun dun lati dárapo mọ ẹgbẹ Arsenal.

O sọ pe oun sí ní ìrètí pé ''àwọn yóò jo ṣé gudugudu meje ati yaya mẹfa pọ''

Àwọn ololufe ẹgbẹ Arsenal ni orílè-èdè Nàìjíríà, si ti n fi iṣẹ ìkínni káàbọ̀ ranṣẹ sí akoni-moogba tuntun wọn

Related Topics