Iniesta: Mo lọ Vissel Kobe fún àgbéga bọ́ọ́lù ní Japan

Iniesta tẹwọ gba aṣọ jẹẹsi rẹ
Àkọlé àwòrán,

Andres Iniesta kúrò ní Barcelona lẹ́yìn ọdún méjìlélógún

Gbajugbaja agbabọọlu Barcelona tẹlẹ, Andres Iniesta ti darapọ mọ ẹgbẹ agbabọọlu Vissel Kobe lorilẹede Japan.

Ni opin saa idije bọọlu ni liigi orilẹede Spain to pari yii ni Iniesta kọwe fi ikọ agbabọọlu Barcelona silẹ ki o to ti ọwọ bọwe adehun olowo-gọbọi pẹlu ẹgbẹ agbabọọlu Vissel Kobe naa.

Nọmba Jẹẹsi kẹjọ ni wọn fun Iniesta ni ẹgbẹ agbabọọlu Vissel Kobe ni ilu Tokyo.

Àkọlé àwòrán,

iniesta ti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Vissel Kobe lórílẹ̀èdè Japan

Ẹgbẹ agbabọọlu Visel Kobe ni eto apejẹ ikinikuabọ too waye fun Iniesta ni ọjọ abamẹta eleyi ti wọn da pe ni "Bienvenido ANDRÉS INIESTA"

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ninu ọrọ to sọ, alaga ẹgbẹ agbabọọlu Vissel Kobe, Hiroshi Mikkya ninu ọrọ ikini kuabọ rẹ ni ireti oun ni wi pe, 'fun Visel Kobe irufẹ bọọlu ti Iniesta mọọ n gba yoo tunbọ mu idagbasoke wa fun wa. Mo mọ pe idarapọ Iniesta yoo bu kun agbara ẹgbẹ agbabọọlu Visel Kobe.'

Àkọlé àwòrán,

Ko si ẹni to mọ iye ti wọn ra Iniesta

Ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu awọn akọroyin, Andres Iniesta ni ọwọ ti oun ni fun ere bọọlu ati awọn agbabọọlu ni orilẹede Japan pọ jọjọ.

"Mo mọ nipa ikọ agbabọọlu orilẹede Japan. Mo wa si orilẹede Japan lati ṣe afihan bọọlu gbigba ati lati ran ẹgbẹ agbabọọlu mi lọwọ. Nipa ṣiṣe bẹẹ, mo lero pe ẹgbẹ agbabọọlu yii ati ere bọọẹu lorilẹede Japan yoo tunbọ tẹsiwaju."

Skip Twitter post, 1

End of Twitter post, 1

Ni bayii, ko tii si ẹni lee sọ ni pato, iye owo adehun ti o wa laarin Iniesta ati ẹgbẹ agbabọọlu Vissel Kobe.