Mohammed Salah fi ìkíni ṣọwọ́ lójú òpó Twitter

Image copyright SERGEI SUPINSKY/AFP/Getty Images)
Àkọlé àwòrán Salah, gbajúgbajà agbábọ́ọ̀lù Liverpool jáde nínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ náà lẹ́yìn tó fi èjìká rẹ̀ ṣèṣe

Ogunna gbongbo agbabọọlu ẹgbẹ Liverpool Mohammed Salah to jade kuro lori papa lẹyin ti o ti fi apa rẹ ṣeṣe ninu ifẹsẹwọnsẹ idije Champions League ti fi ikini ranse si awon ololufe rẹ.

Ikinni naa ni akoko ti yoo fi sowo leyin to fara pa ninu asekagba idije Champions League lojo abameta.

O ni oun ni igbagbo pe ara oun da saka lati le kopa ninu idje ife agbaye to de tan ni orileede Russia.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Image copyright @MoSalah
Àkọlé àwòrán Eyi ni akọkọ ikede lati ọdọ Salah lẹyin igba to fara pa lọjọ abamẹta

Sallah ni ''ale manigbagbe ni o jẹ sugbon akin ni mi. Ifẹ ti ẹ ni simi pẹlu atilẹyin yin yoo ranmi lọwọ lati bori''

Ọpọ awọn ololufe re paapa julo awọn ọmọ orileede Egypt to ti wa ni wọn kaya soke lẹyin ti Salah sese lori papa ni Kiev.

Iroyin orisirisi la si tin gbo nipa ipo alafia rẹ .

Ọrọ to fi sita yi mu ibanikẹdun ati ọrọ iwuri wa lati ọd awọn ololufe rẹ ti wọn si ki loju opo Twitter bakannaa.