Ikọ̀ Super Eagles yóò kojú DR Congo láì bẹ̀rù Ebola

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAgbẹnusọ fun ikọ Super Eagles lori Ebola

Agbẹnusọ fun ikọ Super Eagles, Toyin Ibitoye to ba ilẹ iṣẹ́ iroyin BBC Yorùbá sọrọ sọ pe ko si ifoya kankan lori arun Ebola bi Nigeria yoo ṣe koju DR Congo ninu ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ ọlọ́rẹ̀ẹ́ sọ́rẹ̀ẹ́ nilu Port Harcourt.

O fidi rẹ mulẹ pe awọn eleto ilera ti se ayẹwo finifini fun awọn ẹgbẹ agbabọọlu ilẹ naa, ti wọn si ri i pe ko si ami arun Ebola kankan lara wọn.

O fi kun ọrọ rẹ pe ẹgbẹ agbabọọlu Nigeria naa ti wa ni imurasilẹ latari igbaradi ti wọ ti ṣe fun ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ ọlọ́rẹ̀ẹ́ sọ́rẹ̀ẹ́ ọhun.