Ikọ̀ Super Eagles fẹ́ fàgbà han England fún ìgbà akọ́kọ́

Agbábọ́ọ̀lù William Troost-Ekong Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ikọ̀ Super Eagles yóò koju England ninu ifẹsẹwọnsẹ ọlọrẹẹsọrẹẹ ní pápá ìṣeré Wembley

Ikọ Super Eagles yoo gbiyanju lati fagba han ilẹ Gẹẹsi fun igba akọkọ nigbati wọn ba pade ninu ifẹsẹwọnsẹ ọlọrẹẹsọrẹẹ lọjọ Abamẹta.

Ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles ko tii jawe olubori ninu ifẹsẹwọnsẹ pẹlu ilẹ Gẹẹsi ri lati igba ti wọn ti n pade ara wọn.

Ikọ Super Eagles yoo rinrin ajo lọ si ilu London l'ọjọru fun ifẹsẹwọnsẹ naa ti yoo waye ni papa iṣere Wembley.

Orilẹede Nigeria kuna pẹlu ami ayo kan s'odo nigbati wọn koju ikọ agbabọọlu ilẹ Gẹẹsi l'ọdun 1995.

Ọmi ni wọn ta nigbati wọn pade ninu idije ife ẹyẹ agbaye ti orilẹede Korea ati Japan gbalejo rẹ l'ọdun 2002.

Naijiria ta omi alayo kọọkan ninu ifẹsẹwọnsẹ ọlọrẹẹsọrẹẹ ti wọn gba pẹlu orilẹede DR Congo lọjọ Aje nilu Port Harcourt.

Ẹwẹ, Aarẹ Muhammadu Buhari yoo gbalejo ikọ Super Eagles lọjọ Iṣẹgun ki wọn to maa lọ si ilu London lọjọru.