Zidane: Real Madrid nílò akọ́nimọ̀ọ́gbá míràn

Zinedine Zidane

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán,

Zinedine Zidane ni akọ́nimọ̀ọ́gbá àkọ́kọ́ tó gba ife ẹ̀yẹ Champions League mẹ́ta lẹ́ra wọn

Akọnimọọgba ikọ Real Madrid ti wọn sẹṣẹ gba ife ẹyẹ Champions League ti k'ọwe fipo silẹ lẹyin ọjọ ti wọn gba amin ẹyẹ naa.

Zidane kede igbesẹ naa nibi ipade akọroyin pajawiri lọsan Ọjọbọ nilu Madrid.

Ninu ọrọ rẹ, Zidane sọ ọ di mimọ pe, ikọ Real Madrid nilo ẹlomiran lati dari ẹgbẹ agbabọọlu naa.

Zidane to fi gba kan jẹ agbabọọlu fun ikọ Real Madrid gba ife ẹyẹ Champions League mẹta laarin ọdun meji abọ to fi tukọ ẹgbẹ agbabọọlu naa.

Zidane tun gba Liigi La liga pẹlu Real Madrid lẹkan ni akoko rẹ gẹgẹ bi akọnimọọgba ikọ agbabọọlu naa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Real Madrid gba ife ẹ̀yẹ Champions League mẹ́ta ati La Liga kan nígbàti ó tukọ̀ ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù náà

Akọnimọọgba naa to jẹ ọmọ ọdun mẹtadinlaadọta sọ pe o nira fun oun lati gbe igbesẹ naa ṣugbọn o sọ pe akoko ti to.

Ẹwẹ, agbaọjẹ meji agbabọọlu Real Madrid, Cristiano Ronaldo ati Gareth Bale naa ti sọ tẹlẹ pe bo ya lawọn o tẹsiwaju pẹlu ikọ naa.