Frank Lampard: Ìbí kò ju ìbí láàrin àwọn agbábọ́ọ́lù mi

Aworan Frank Lampard

Oríṣun àwòrán, @dcfcofficial

Àkọlé àwòrán,

Ìbí pẹlẹbẹ láa ti mú ọle jẹ́. Ìṣẹ n bè níwájú wà

Gbajugbaja agbaboolu ẹgbẹ ọmọ orílè-èdè Gẹẹsi Frank Lampard ti gba iṣẹ́ akoni-moogba ẹgbẹ́ agbaboolu Derby County.

Ìkéde iyansipo náà wáyé lọjọ́rú.

Èyí ni iṣẹ akọni akọkọ tí Lampard yóò gbà lẹyìn tí o feyinti nìdí bọọlu gbígbà.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Níbi ìpàdé akoroyin àkọkọ rẹ fún ẹgbẹ náà, Lampard ní òun ṣetan láti ṣe nkán òun lona ti tóun.

"Mí o dàbí ẹnikẹni lara awon akoni-moogba ti mo ti bá ṣíṣe sẹyìn. Lodo témi bákannáà lọmọ ṣe orí nípa àwọn agbaboolu mí"

Ọdún mẹta ni Lampard t'ọwọ bọ àdéhùn pẹlú ẹgbẹ náà.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ifẹsẹwọnsẹ ìkẹyìn Lampard ni Premiere wáyé fún Man City nígbà tí wọn kojú Southampton ni oṣù karun ọdún 2015

Alága ẹgbẹ́ agbaboolu Derby County, Mel Morris ni, àwọn yóò ṣe suru pẹlú Lampard ''sugbọn eyi ko tunmọ si pe a ko ni ni afojusun.''

Gary Rowett ni akọnimoogba to fi ipò sílẹ ṣáájú Lampard.