Oyún ṣíṣẹ́: Wíwá òògun ìsẹ́yún lórí àyélujára peléke síi

Foonu àti ọwọ to ń tẹẹ
Àkọlé àwòrán Ìwádìí fi hàn pé àwọn orílẹèdè tó fi òfin de ìsẹ́yùn ni ó pọ̀jù nínú àwọn tó ń ṣe ìwádìí òògùn oyún ṣíṣẹ́ lórí ìtàkùn àgbáyé.

Ìwádìí BBC lórí àbẹwò sórí ìtàkùn àgbáyé ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé, àwọn tó ń wádìí òògùn ìṣẹ́yún lóri ẹ̀rọ ayélujára lágbàyé láti ǹkan bí ọdún mẹwàá sẹ́yìn tí di ìlópo méjì.

Ìwádìí náà tún pe àkíyèsí síi pé, àwọn orílẹèdè tí òfin kò fààyè gbà láti máa sẹ́yùn ni ó pọ̀jù, nínú àwọn tó ń ṣe ìwádìí òògùn oyún ṣíṣẹ́ lórí ìtàkùn àgbáyé.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ọ̀pọ̀ àwọn obirìn ló ti di onímọ̀ nípa ọ̀nà ìmọ̀-ẹ́rọ, tí wọn sì tí gbé ìdíwọ́ òfin tó de ìṣẹ́yún tì sẹ́gbẹ̀ kan.

Nípa ríra òògùn ìṣẹyún lórí ayélujára àtí ṣíṣe ìwádìí nípà ìṣègùn lóri àtèjíṣẹ́ WhatsApp, ọ̀pọ̀ àwọn obirìn ló ti di onímọ̀ nípa ọ̀nà ìmọ̀-ẹ́rọ, tí wọn sì tí gbé ìdíwọ́ òfin tó de ìṣẹ́yún tì sẹ́gbẹ̀ kan.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nigeria àti Ghana jẹ́ orílẹ̀-èdè méjì tí ìwádìí nipa òògùn ìṣẹ́yún Misoprostol lórí ayélujára tí gbilẹ̀ jùlọ, gẹ́gẹ́ bíí goggle ṣe sọ.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ofín tirẹ̀ le púpọ̀ fún ìṣẹ́yún tí wọn fi ààyè gba ìṣẹyún tí obìnrin náà bá wà nínú ewu nìkan.

Ní ti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ofín tiẹ̀ le púpọ̀ fún ìṣẹ́yún, àmọ́ wọn fi ààyè gba ìṣẹyún tí obìnrin náà bá wà nínú ewu nìkan

Ní orílẹ̀-èdè Ghana, wọ́n fààyè gba oyún ṣíṣẹ́ tí wọn bá fi ipá bá obìnrin lò pọ̀, tí baba bá bá ọmọ rẹ̀ lò pọ̀, tí ọmọ inu bá jẹ́ aláàbọ̀ ara tàbí tí oyún inú náà bá le sọ obìnrin di ọlọ́dẹ orí.

Àkọlé àwòrán Orílẹ̀-èdè márùndínlọ́gbọ̀n tí ó ń wá òògùn ìṣẹ́yún jùlọ lórí goggle fún Misoprostol wá láti Afíríkà, mọ́kànlá nínú wọn wá láti ilẹ̀ Afíríkà tí àwọn mẹ́rìnlá tó kù sì jẹ́ Latin America.

Nínú gbogbo orílẹ̀-èdè márùndínlọ́gbọ̀n, tí ó ń wá òògùn ìṣẹ́yún jùlọ lórí goggle fún Misoprostol, mọ́kànlá nínú wọn wá láti ilẹ̀ Afíríkà, tí àwọn mẹ́rìnlá tó kù sì jẹ́ Latin America.