NFF àtàwọn olólùfẹ̀ eré bọ́ọ̀lù ń ṣe ìdárò Big Boss: Keshi

Olóògbe Stephen Keshi

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Olóògbe Stephen Keshi fìgbà kan jẹ́ akọ́nimọ̀ọ́gbá ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù orílẹ́lèdè Togo

O pé ọdun meji ti akọnimọọgba ikọ Super Eagles, Stephen Keshi, jade laye lẹyin iku aya rẹ̀.

Ajọ to n ri si ere bọọlu l'orilẹ-ede Naijiria NFF ati awọn ololufẹ ere bọọlu n ṣe ranti agbaọjẹ akọnimọọgba ni Naijiria ati kakiri agbaye naa.

Keshi di oloogbe l'ọjọ keje, oṣu kẹfa, ọdun 2016 ni ilu Benin ni ipinlẹ Edo.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Aisan ọkan lo mu Keshi lọ nigba to pe ọmọ ọdun mẹrinlelaadọta.

Keshi, to jẹ adiẹyinmu fun ikọ Super Eagles tẹlẹ ri, ṣoju orilẹ-ede Naijiria ninu idije ife ẹyẹ Ilẹ Afirika lẹẹmẹrin ati ife ẹyẹ agbaye lẹẹkan l'ọdun 1994.

Ajọ NFF ṣe iranti rẹ lori opo Twitter, wọn kii fun ọpọlọpọ aṣeyọri to ṣe ninu ere bọọlu l'orilẹ-ede Naijiria

Keshi ni akọnimọọgba to ko ikọ Super Eagles lọ si ife ẹyẹ agbaye ọdun 2006.

O gba ami ẹyẹ idije bọọlu Ilẹ Afirika gẹgẹ bi akọnimọọgba ni ọdun 2013, o si tun gbaa gẹgẹ bi agbabọọlu l'ọdun 1994.