World Cup 2018: Nàíjíríà yóò dé Semi-final- Elẹ́dẹ̀ Àràmàǹdà

Marcus the Mystic
Àkọlé àwòrán,

Elẹ́dẹ̀ náà sọtẹ́lẹ̀ pé Nigeria, Belgium, Uruguay ati Argentina yóò kópa ní ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ tó kángun sí àsekágbá Ife Ẹ̀yẹ Agbaye Russia 2018.

Ẹranko aramanda kan ti sọ asọtẹlẹ pe Naijiria pẹlu awọn orilẹede mẹrin miran ni yoo kopa ninu ifẹsẹwọnse to kangun si asekagba Ife Ẹ̀yẹ Agbaye Russia 2018.

Ẹlẹdẹ aramanda naa ti wọn pe orukọ rẹ ni, Mystic Marcus ni ilu Heage ni Ilẹ Gẹsi ni Nigeria pẹlu Belgium, Uruguay ati Argentina ni awọn agbabọọlu orilẹede ti yoo kopa nibi ifẹsẹwọnsẹ to kangun si asekagba naa.

Olootu ẹlẹde naa, Juliette Stevens sọ wi pe asọtẹlẹ ẹlẹdẹ naa daju nitori igba akọkọ kọ ni yiI ti ẹẹdẹ naa yoo sọ asọtẹlẹ ti yoo si wa si imusẹ.

Àkọlé fídíò,

Russia 2018:Super Eagles ti kẹ́kọ̀ọ́ nínú ìdíje tó kọjá

O ni ẹlẹdẹ naa to jẹ ọmọ ọdun mẹjọ sọ asọtẹlẹ wi pe Donald Trump yoo di Aarẹ Ilẹ Amẹrika, ati wi pe Ilẹ Gẹẹsi yoo kuro ni Ajọ Europe.