World Cup 2018: Coper ní Salah ti pada bọ̀ sípò dáadáá

Mojamed Salah

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Salah ló gba àmì ẹ̀yẹ̀ ẹlẹ́sẹ̀-ayò tó gbá bọ́ọ̀lù sáwọ̀n jù nínú ìdíje Premier League ní sáà tó kọjá

Akọnimọọgba fẹgbẹ agbabọọlu Egypt, Hector Cuper sọ pe, ẹlẹsẹ-ayo Mohamed Salah ti ṣetan, lati kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ wọn pẹlu ikọ Uruguay ninu idije ife ẹyẹ agbaye Russia 2018 l'ọjọ Ẹti.

Salah ko ti kopa ninu ere bọọlu kankan, lati igba to ti ṣeṣe pẹlu ejika rẹ ninu ifẹsẹwọnsẹ aṣekagba idije Champions League, laarin Liverpool ati Real Madrid l'osu karun un.

Akọnimọọgba Cuper sọ di mimọ pe, ara Salah ti bọ sipo ni kikun, o si ti ṣetan lati ṣoju orilẹede Egypt.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Cuper tun fọwọ ṣọya pe Salah lanfani lati gba ami ẹyẹ ẹlẹsẹàyo,ti yoo gba bọọlu sawọn julọ ninu idije ife ẹyẹ agbaye l'orilẹede Russia.

O fi kun ọrọ rẹ pe, adiẹyinmu Ali Gabr naa yoo kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ akọkọ, ti orilẹede Egypt yoo gba nilẹ Russia.

Ẹwẹ, o ṣeeṣe ki ẹgbẹ agbabọọlu alatako wọn, Uruguay, lo awọn ọjẹ-wẹwẹ agbabọọlu aarin gbungbun, nigbati wọn ba koju Egypt ní ọ̀la òde yìí.