World Cup 2018: Russia gbá márùn ún wọlé sáwọ̀n Saudi lófo

Àwọn agbábọ́ọ̀lù orílẹ́èdè Russia

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Russia jáwé olúborí nínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ àkọ́kọ́ ní World Cup 2018

Orílẹ̀-èdè Russia, to n gbalejo Ife ẹyẹ agbaye 2018 fakọyọ, ninu ifẹsẹwọnsẹ akọkọ ninu idije naa, lẹyin ti wọn fagba han Saudi Arabia pẹlu àmì ayo marun un sodo.

Ọmọ orilẹede Russia, Yuri Gazinskiy, náà tún ni ẹni to kọkọ gba bọọlu sawọn, ninu idije naa lẹyin to gba ayo wọle ni iṣẹju mejila ti wọn bẹrẹ.

Denis Cheryshev ati Aleksandr Golovin gba ayo meji-meji sile Saudi Arabia, bi Russia ti n da bi ẹdun, ti wọn si n rọ bi owe ninu ifẹsẹwọnsẹ naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Russia 2018:Super Eagles ti kẹ́kọ̀ọ́ nínú ìdíje tó kọjá

Ifẹsẹwọnsẹ miran ni isọri akọkọ ti Russia wa, ni yoo waye laarin Egypt ati Uruguay lọjọ Ẹti.