Wo àwọn ẹlẹ́sẹ̀ ayò ti wọ́n ti rọ́wọ́mú nidije World Cup

Agbabọọlu Uruguay Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Eyi kọja bẹẹ, gbogbo ara la fi n gbá bọọlu lasiko yii

Ìdíje mẹrin ló ti wáyé báyìí látigba ti World cup 2018 ti bẹ̀rẹ̀ ni Russia.

Ìdije laarin orilẹ-ede Russia to ń gbàlejò àti Saudi Arabia ni wọn kọkọ fi ṣide ife ẹyẹ agbaye World Cup 2018.

ÀWỌN ORILẸ-EDE TO KOJU ARA WỌN ESI IDIJE WỌN
Russia vs Saudi Arabia 5-0

Lẹyin èyí ni àwọn orilẹ-ede mẹfa miran jọ ná an tán bi owó pẹlu èsì wọnyii:

ÀWỌN ORILẸ-EDE TO KOJU ARA WỌN ESI IDIJE WỌN
Egypt vs Uruguay 0-1
Iran vs Morocco 1-0
Portugal vs Spain 3-3

Awọn orilẹ-ede to gbegba oroke ri atilẹyin awọn ẹlẹse ayo bii:

  • Jose Gimenez ati Carlos Sanchez fun Uruguay ti wọn fi jawe olubori.
  • Ẹlẹ́sẹ̀ oró, Aziz Bouhaddouz, ti Morocco to ṣeeṣi gba bọọlu naa sáwọ̀n ile ara rẹ (Morocco).
  • Cristiano Ronaldo to gba bọọlu sáwọ̀n Spain lẹẹmẹta ọtọọto
  • Diego Costa gba meji sáwọ̀n Portugal.
  • Nacho Fernandez gba ọkan sáwọ̀n Portugal ti wọn fi ta ọmi.

Èyí ni díẹ̀ lára àwọn àwòràn àwọn ẹlẹ́sẹ̀ ayò náà lẹnu iṣẹ́ wọn lọkọọkan:

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Idunnu ṣubu layọ lẹyin ti Russia sọ bọọlu sáwọ̀n Saudi Arabia
Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán 'A kò róhun fáyọ̀ bi ko ba ṣe ọpẹ'
Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ìdí iṣẹ́ ẹni la ti ń mọ ni lọ́lẹ́, ọrọ eré bọọlu ti gba ìṣirò bayii.
Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán 'Bóò lọ, o yàá mi ni ìṣesí àwọn agbabọọlu to n kopa ninu ìdíje World Cup 2018 ni Russia'
Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ẹni à ń bá ná ọjà là ń wò, a kìí wo ariwo ọjà ràrà ló bá dé nńú ìdíje ife ẹyẹ àgbáyé 2018
Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ronaldo ti Portugal, ẹlẹ́sẹ̀ ayò ilẹ̀ Portugal lo ti gbá àmì ayò tó pọ̀jù lọ (3) nidije
Image copyright Huw Evans picture agency
Àkọlé àwòrán Ìrìrì kọjá ẹgbẹ́ abewu lọrọ eré bọọlu di bayii
Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ayọ̀ ti kò lẹ́gbẹ́ ni ti èèyàn sọ bọọlu sáwọ̀n ẹlomii

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionGbolahan Kabiawu: Fífi ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ dára fún ẹ̀yà ara
Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ajanaku kọja mo ri nkan firi ni idje bóólu di bayii