World Cup 2018: France ṣíná fún Australia nísọ̀rí kẹta

Paul Pogba Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Antoine Griezmannn ati Paul Pogba ti France lo gba bọlu wọ inu awọn fun France ni Ife Ẹyẹ Agbaye to n lọ lọwọ

Ife Ẹyẹ Agbaye ti Russia 2018 to n lọ lọwọ n gbona fẹlifẹli sii ni lojoojumọ.

Ninu idije to pari ni orilẹ-ede France ti fagba han Australia pẹlu ami ayo meji si eyọkan.

Ikọ France ati ikọ Australia wa ni isọri kẹta Ife Ẹyẹ Agbaye to n lọ lọwọ

Antoine Griezmannn lo kọkọ gba bọọlu kọjú-sími-gbáa-sílé wọ le fun orilẹ-ede France ko to di pe Paul Pogba tun gba bọọlu wọ inu àwọ̀n fun ilẹ France.

Australia da ẹyọkan pada lẹyin ti rẹfiri fun wọn ni bọọlu kọjú-sími-gbáa-sílé, ti Mile Jedinak si gba a wọ inu àwọ̀n.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionRussia 2018: Nàìjíríà dúró gìdìgbà, ki Ọlọrun fún wa ṣe

France nireti pe wọn a tun fakọyọ sii nigba ti wọn ba n fẹsẹwọnsẹ pẹlu orilẹ-ede Peru ni Ọjọbọ ọsẹ to n bọ, nigba ti Australia yoo ma a koju Denmark.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionGbolahan Kabiawu: Fífi ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ dára fún ẹ̀yà ara