Ìkọlù Borno: Obìnrin mẹ́fà ló gbé àdò olóró ní Borno

Àwọn tií ìsípò padà dé bá Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Báyìí ni àwọn tó sá ń'lé ní Damboa àtàwọn ìlú mìí se ń gbé ní ibùdó tí wọ́n sá lọ

Àwọn òsìsẹ́ aláàbò lórílẹ̀èdè Nààjíríà sọ pé àwọn obìnrin agbé àdò olóró ló se ọṣẹ́ tó wáyé ní ìlú apá ìlà oòrùn àríwá Nàìjíríà, Damboa.

Ó lé ní ogójì ènìyàn tó farapa nínú ìbúgbàmù náà báyìí èyí tó wáyé lálẹ́ ọjọ́ àbámẹ́ta.

Kò tíì sẹ́ni tó fojú hàn gẹ́gẹ́ bí ẹni tó sokùnfà rẹ̀ sùgbọ́n òjú ni kìí se àìmọ̀ f'ólóko pé ikọ̀ Boko Haram máa ń ṣ'ọṣẹ́ ní agbègbè náà.

Awọn iroyin miran ti ẹ le nifẹ si:

Adó olóró méjì to bu gbamu yìí ti pa eniyan mọkanlelọgbọn ni ìlú Damboa, ìpínlẹ̀ Borno, ní apá ìlà oòrùn àríwá Nàìjíríà.

Isẹlẹ náà waye lẹyin wakati diẹ ti Ọ̀gá àwọn ọmọ ogun oríilẹ̀ orílẹ̀èdè Nàìjíríà, Ọ̀gágun Tukur Buratai ní kí àwọn ènìyàn apá ìlà oòrùn àríwá padà sí ilé wọn.

Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Ọ̀gágun Tukur Buratai ní kí àwọn ènìyàn apá ìlà oòrùn àríwá padà sí ilé wọn

Burutai rọ àwọn ará ìlú tí ogun lé kúrò nílé láti padà nítorí pé àláfíà ti jọba lagbeegbe naa.

Lẹ́yìn ìbúgbàmù ọ̀ún ni iná rọ́kẹ̀tì láti ìlú míì tún tú jáde.

ìròyìn ní obìrin ní àwọn agbésùmọ̀mí mẹ́fà tó siṣẹ́ ọ̀hún bótilẹ̀ jẹ́ pe àwọn Boko Haram kò tí jáde wá pe àwọn ní àwọn ṣe ìkọ́lù ọ̀hún.

Ènìyan tó lé ní ogojì ló farapa ninu isẹlẹ ibugbamu naa.