Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ́lù AS Roma dá sí awuyewuye jọ̀lọ́fù

Ìrẹsi tí Naijiria n jẹ

Oríṣun àwòrán, NDUDU BY FAFA

Awuyewuye to wa lori orilẹ-ede to ni irẹsi jọlọfu to dara ju ti de ibi ti eniyan ko tilẹ lero bayi - ọdọ ẹgbẹ agbabọọlu Italy ti orukọ wọn n jẹ AS Roma.

Ẹgbẹ agbabọọlu naa gbe idibo ori ayelujara kan jade lori Twitter lati fun awọn eniyan lanfani lati dibo fun orilẹ-ede ti wọn ro pe jọlọfu rẹ dara ju.

Orilẹ-ede Naijiria, Ghana, Liberia ati Senegal ni orilẹ-ede mẹrin ti awọn eniyan ti lanfani lati mu ọkan.

Igbesẹ AS Roma naa ya ni lẹnu pupọ, ṣugbọn awọn akopa ninu idibo naa fi han pe jọlọfu Naijiria ni awọn fẹran ju nitori orilẹ-ede naa ko ida mọkanlelaadọrin gbogbo ibo awọn akopa.

Ti ẹ ba ranti, aarẹ ẹgbẹ́ àgbẹ̀ onìrẹsì ní orílẹ̀-ède Nigeria (RIFAN), Aminu Goroyo, sọ fún BBC pé, tọ́ọ́nù mẹ́sàn àti ààbọ mílíọ́nù ìrẹsì ni àwọn ọmọ Naijiria ń jẹ lọ́dọọdún.

Goroyo ní, bíi ìdá mẹ́sàń nínú mẹ́wáà ìrẹsì tí ọmọ Naijira ń jẹ ní àwọn àgbẹ̀ orilẹ̀èdè yí ń gbìn fúnra wọn.

Mílíọ́nù mẹ́sàn àti ààbọ tọ́ọ́nù ìrẹsì (9.5 million MT) já sí bílíọ́nù mẹ́sàn àti ààbọ kílò (9.5 billion KG) ìrẹsì. Èyí náà wá já sí àádọ́wà mílíọ́nù àpò ìrẹsì (190).

Àgbékalẹ̀ rẹ̀ rèé:

Ní ọjọ́ Ajé ni Mínísítà fún Ètò Ọ̀gbin, Audu Ogbeh ké gbàjarè pé orílẹ̀èdè kan ń pèsè ìrẹsì olóró.

Ogbeh ní tí Naijiria kò bá jáfara, irẹsì náà yóò wọnú orílẹ̀ède yí láti ẹnu ibodè.

Àkọlé fídíò,

Ọọni Ile-Ifẹ: Gbogbo olùdìbò ló ní agbára ti rẹ̀.

Nítorí náà ni ó ní ìjọba àpapọ̀ yóò ti ibodè rẹ̀ pẹ̀lú orilẹ̀èdè n láti ríi pé àwọn onífàyàwọ́ kò kó oúnjẹ náà wọlé.

Àjọ àgbáyé tọ ń rí sí ọ̀rọ̀ oúnjẹ (FAO) sọ wípé, Naijiria jẹ́ ọ̀kan lára àwọn orílẹ̀ède tó ń jẹ ìrẹsì jú ní àgbáyé,

Báwo ni ẹ ṣe ń jẹ ìrẹsì tó nínú ilé yín?

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Orísi ọ̀gẹ̀dẹ̀: Sàró lo mọ̀ ni àbí Pàǹbo?