World Cup 2018: Ronaldo ti gbá ayò mẹ́rin sáwọ̀n

Cristiano Ronaldo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Àgbà ọ̀jẹ̀ agbábọ́ọ̀lù, Cristiano Ronaldo ti fakọyọ nínú ifẹsẹ̀wọnsẹ̀ méjì tó tii gbá nínú ìdíje ife ẹ̀yẹ àgbáyé tó ń lọ lọ́wọ́

Agba-ọjẹ ẹlẹsẹ-ayo, Cristiano Ronaldo, lo n gbegba oroke bayi ninu awọn to ti gbabọọlu sawọn julọ ninu idije ife ẹyẹ agbaye to n lọ lọwọ l'orilẹede Russia.

Ronaldo lo gba bọọlu sawọn bi Portugal ṣe fagba han ikọ Morocco pẹlu ami ayo kan sodo lọjọ Ọjọru.

Ayo mẹrin ni Ronaldo ti gba sawọn bayi nínú ìdíje ife ẹ̀yẹ àgbáyé tó ń lọ lọ́wọ́ lẹyin to gba bọọlu sawọn lẹmẹta nigbati Portugal koju Spain ninu idije akọkọ wọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Àgbà ọ̀jẹ̀ agbábọ́ọ̀lù, Cristiano Ronaldo ti fakọyọ nínú ifẹsẹ̀wọnsẹ̀ méjì tó tii gbá nínú ìdíje ife ẹ̀yẹ àgbáyé tó ń lọ lọ́wọ́

Diego Costa ti ilẹ Spain, Harry kane to jẹ ọmọ England ati Romelu Lukaku agbabọọlu fun orilẹede Belgium, ni gbogbo wọn ni ami ayo mejimeji.