World Cup 2018: Àwọn ọmọ orílẹ̀èdè Japan di agbálẹ̀ ní Russia

Awọn ololufẹ bọọlu

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán,

Àwọn ọmọ oríllèdè Japan kò le pa ìdùnnú wọn mọ́ra

Ohun tó wọ́pọ̀, lẹ́yìn ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ tó gbóná nínú ìdíje ife àgbáyé ni pé, ki awọn ààyè ìjókò kún fún abọ́ oúnjẹ, ife àti ọ̀rá lóríṣiríṣí .

Ṣùgbọ́n ohun àrà ní iṣesi àwọn alátìlẹyìn eré bọ́ọ̀lù tó jẹ́ ọmọ orilẹ̀èdè Japan se, lẹ́yìn ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ àkọ́kọ́ tí Japan ní pẹ̀lú Colombia, níbi tí wọ́n ti jáwé olúborí.

Téègún ẹni bá jóòre, orí a maa ya atọkun rẹ̀, láwọn ọmọ orilẹede Japan tó lọ si Russia, lati ṣe koriya fun ẹgbẹ́ agbabọọlu wọn, fi ọ̀rọ̀ sẹ, pẹ̀lú bi wọn ṣe sọra wọn di agbalẹ ọsan gangan ní papa isẹre, lẹyin ti ẹgbẹ agbabọọlu Japan fiya jẹ Colombia pẹlu ami ayo meji si ẹyọ kan lọjọ Iṣẹgun.

Niṣe ni awọn ololufẹ bọọlu ọhun gbe awọn apo idalẹ nla-nla dani, ti wọn si n to lọwọọwọ gba ibi ti wọn joko si lati wo bọọlu, ti wn si bẹrẹ si ni ṣa idọti loriṣiriṣi, pẹlu afojusun lati fi ibẹ silẹ ni mímọ́ tóní-tóní, gẹ́gẹ́ bí wọn ṣe ba a.

Ìgbà akọkọ kọ niyii ti àwọn alatilẹyin ẹgbẹ agbabọọlu Japan yoo ṣe bẹẹ, 'wọn ki i fi ẹkọ ile naa ṣere rara.'

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán,

Tijó-tayọ̀ ni wọn fi yẹ́ àwọn agbábọ́ọ̀lù wọn sí

Ọmọ orilẹede Japan kan, to jẹ akọroyin ere bọ́ọ́lù sọ fun BBC pe, ihùwàsí awọn ọmọ orilẹede Japan ọhun kii ṣe fun idije bọọlu nikan, ṣugbọn o jẹ ọkan gboogi lara aṣa Japan.

O ni "Nkan pataki to wọpọ ni awujọ orilẹede Japan ni lati ri daju pe, "ohun gbogbo wa ni mimọ toni-toni, eyi ko si yọ gbogbo idije ere idaraya silẹ."