World Cup 2018: Kìlódé tí kòsí àkọ́nimọ̀ọ́gbá láti ilẹ̀ adúláwọ̀?

Mbaye Niang lọ̀jọ June 19, 2018 ni Moscow, Russia Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Awọn ikọ Senegal dunnu lẹyin ti wọn na Poland pẹlu ami ayo 2-1

Senegal gba ògo fún Afrika nínú ìdíje àti níni akọnimọọgba Adulawọ kan ṣoṣo ni Russia.

Senegal nikan lorilẹ-ede lati ilẹ Afirika to jawe olubori ninu ifẹsẹwọnsẹ alakọkọ ni isori won, lẹyin ti wọn lu awọn ikọ agbabọọlu to wa lati ilẹ Afirika ni alubami ni isọri wọn.

Akọnimọọgba ilẹ Senegal, Aliou Cisse, nikan lo jẹ akọnimọọgba alawọdudu ninu awọn orilẹ-ede mejilelọgbọn to n kopa ninu idije naa.

Cisse ninu ọrọ rẹ sọ pe lootọ ni pe oun nikan ni akọnimọọgba to jẹ ọmọ ilẹ Afrika, amọ o wi pe idije erebọọlu wa fun gbogbo agbaye ni ati fun gbogbo eniyan, ti ko si niise pẹlu awọ ara.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÌran ni oúnjẹ ojú ni ọ̀rọ̀ ife ẹ̀yẹ Russia 2018 dì báyìí

Iroyin sọ pe awọn akọnimọọgba to jẹ alawọ dudu ṣọwọn ni Idije Ife Ẹyẹ Agbaye, bi o tilẹ jẹ pe wọn fikun awọn orilẹ-ede to n kopa lati orilẹ-ede mẹrinlelogun si mejilelọgbọn.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Nínú àwọn orílẹ̀èdè 32 tó ń kópa lọ́wọ́ nínú Ìdíje Ife Agbaye 2018, àkọ́nimọ̀ọ́gbá ikọ̀ Senegal, Aliou Cisse nìkan ló wà láti Afirika.

‘ Ilẹ Adulawọ fẹran akọnimọọgba lati ilẹ okeere’

Ninu Idije Ife Agbaye ti 1998 ni orilẹ-ede Faranse, ko si akọnimọọgba to jẹ alawọdudu, bi o tilẹ jẹ pe awọn agbabọọlu lati ilẹ Afirika pọ ninu idije naa.

Lati igba naa, akọnimọọgba meje nikan lo ti laaye lati kopa ninu Idije Ife Ẹyẹ Agbaye.

Bakan naa, ninu Idije Ife Agbaye ti ọdun 2010 to waye ni orilẹ-ede South Africa, ko si akọnimọọgba alawọ dudu kankan.

Ninu ọrọ rẹ, akọnimọọgba fun orilẹ-ede Democratic Republic of Congo, Florent Ibenge, sọ fun Ileesẹ Iroyin AFP pe oun to wọpọ n i ilẹ Afirika ni ki wọn maa lo akọniọọgba lati Ilẹ Gẹẹsi ati orilẹ-ede Amẹrika.

Sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ikọ̀ tí yóò gba ife ẹ̀yẹ àgbáyé 2018 pẹ̀lú eré ìdárayá tuntun ti BBC

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Mi ò ní wo bọ́ọ̀lù mọ́ ti Nàìjíríà bá fìdírẹmi ni Russia 2018'