World Cup 2018: England pegedé fún ìpele kejì ní Russia

Harry Kane Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Harry Kane ló ń ṣíwáájú nínú àwọn tó ti gbá bọ́ọ̀lù sáwọ̀n jù ní Russia pẹ̀lú àmì ayò márùn ún

Ikọ England fiya jẹ Panama pẹlu ami ayo mẹfa ṣi ẹyọkan ninu idije ife ẹyẹ agbaye World Cup 2018 to n lọ lọwọ l'orilẹede Russia.

Ayo mẹta ọtọtọ ni ẹlẹsẹ ayo Harry Kane gba sawọn bi ikọ England ti pegede bayi lati kopa ninu ipelekeji idije ife ẹyẹ agbaye t'ọdun yii.

Adiẹyinmu fun ẹgbẹ agbabọọlu Manchester City John Stones naa fakọyọ ninu ifẹsẹwọnsẹ ọ'un lẹyin igbati o gbayo meji sawọn.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÌyìn, ati ìmọ̀ràn fún Super Eagles
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionWorld Cup 2018: Àwọn ọmọ Nàíjíríà kún fáyọ̀ lóri Super Eagles
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Ìjọba APC ní láti tún wọlé lẹ́ẹ̀kan síi'

Jesse Lingard to n gba bọọlu fun Manchester United naa ko gbẹyin bi o ti gba ami ayo kan sawọn.

Felipe Baloy dayo kan pada ninu mẹfa fun ikọ Panama, ṣugbọn ẹpa ko boro mọ.

Eyi ni igba akọkọ ti ikọ England yoo gbayo mẹrin okere tan wọle ninu ifẹsẹwọnsẹ kan ninu idije ife ẹyẹ agbaye lati ọdun 1966.