Genort Rohr: Kò sí ayé fún ìrégbè lònìí rárá

Awọn agbaboolu Naijiria n gbaradi

Oríṣun àwòrán, @NGSuperEagles

Àkọlé àwòrán,

Awọn agbaboolu Naijiria gbodo gbena koju Argentina ninu ifẹsẹwọnsẹ alẹ oni

Pápá iṣere St Petersburg yóò gbà alejo l'alẹ oni nigba ti ìkọ Super Eagles orílèèdè Naijirià yóò wọ̀'yá ìjà pẹlú Argentina nínú ifẹsẹwọnsẹ asekagba ìsọ̀rí kẹrin abala ìkííní ìdíje àgbáyé.

Ṣáájú ifẹsẹwọnsẹ náà, akọ́ni-mọ̀ọ́gbá ikọ Super Eagles Genort Rohr ti rọ awọn agbaboolu rẹ láti má f'aye silẹ fún àṣìṣe ki wọn sì lo anfààní tó bá jẹyọ fún wọn.

Ifẹsẹwọnsẹ náà je èyí tó lè ṣe okunfa yálà itẹsiwaju tàbí fífi ìdí rẹmi fún ìkọ Super Eagles.

Ogun ní ọrọ tó wà nílẹ̀ yìí

Odion ighalo to jẹ́ atamatase fún ìkọ Super Eagles ní ohun tó bá gba ni awọn yóò fún Argentina nitori pé àwọn ti pinu lati tẹ̀síwájú lọ abala to kan nínú ìdíje àgbáyé.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Odion Ighalo ko ti ni anfaani ati je goolu kankan ninu idije agbaye ni Russia

Nigba ti o n ba ìkọ BBC sọrọ, o ní Argentina yóò múra pàdé àwọn pẹlú gbogbo ọnà ní sùgbọ́n o da oun loju pe àwọn yóò bóri Argentina.

Eyi ni igba ikarun ti Nàìjíríà yóò ma ko'ju Argentina nínú ìdíje àgbáyé.

Ìṣirò bẹrẹ ni pẹrẹwu

  • Croatia tí pegede láti kópa nínú abala tó kan lẹyìn tí wọn gbo ewuro sójú Super Eagles àti Argentina.
  • Argentina àti Iceland ni ayo kọọkan ti anfààní si wa fún àwọn náà láti tẹsíwájú nínú ìdíje àgbáyé.
  • Ayo meji sí odò ti Nàìjíríà gba pẹlu Iceland fun won ni àmì mẹta.
  • Argentina gbọdọ na Nàìjíríà bi wọn bá fẹ́ tèsíwájú.
  • Tí Croatia ba na Iceland, Nàìjíríà le tẹsiwaju pẹlú ami kàn.
  • Ni idakeji, Argentina le tẹsíwájú ti wọn bá na Nàìjíríà ti Croatia si na Iceland.