World Cup 2018: Ṣé àwọn tó kù ní Moscow ló tó gbangba sùn?

Awọn agbabọọlu Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán England àti Croatia; ipade tun di ọdún míràn!

Ọjọ́ Abamẹta nidije ipò kẹta ti waye nigba ti ife ẹyẹ yóò doríkọ orilẹ-ede tó fẹ́ loni.

Ipele kò-mẹsẹ̀-o-yọ nìdíje dé, O ku orilẹ-ede meji pere ni Russia, iyẹn France ati Croatia nigba ti Belgium ti gba ipo kẹta lẹyin ti wọn ṣíná fún England.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán France pegede de ipele aṣekagba World Cup 2018

Àwọn orilẹ-ede ilẹ Adulawọ maraarun ni wọn ti já ti onikaluku ti pada sile. Awọn naa ni: Naijiria, Egypt, Morocco, Tunisa ati Senegal.

Saudi Arabia, Iran, Australia, Iceland, Peru, Costa Rica, Serbia, South Korea, Panama, ati Poland pẹlu awọn miran naa ti ja ninu idije.

Nigba ti àwọn àgbà ọ̀jẹ̀ bii Germany to gba ife ẹyẹ gbẹyin paapaa ti kuro ni Russia pada sile.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Idije ife ẹyẹ agbaye n pari lọ

Ipele kò-mẹsẹ̀-o-yọ nidije déé duro bayii ni Russia ti ẹnikẹni to ba ti fidi rẹmi n pada sile.

ÌSÒRÍ ORILẸ-EDE TO KOPA KINI WỌN GBÁ? ỌJỌ WO NI WỌN GBÁ IDIJE WỌN?
IKINI FRANCE VS ARGENTINA 4-3 30-06-2018
IKINI URUGUAY VS PORTUGAL 2-1 30-06-2018
IKINI SPAIN VS RUSSIA 1-1 (KOJU SIMI GBAA SILE 4-3) 01-07-2018
IKINI CROATIA VS DENMARK 1-1 (KOJU SIMI GBAA SILE 3-2) 01-07-2018
IKINI BRAZIL VS MEXIKO 2-0 02-07-2018
IKINI BELGIUM VS JAPAN 3-2 02-07-2018
IKINI SWEDEN VS SWITZERLAND 1-0 03-07-2018
IKINI COLOMBIA VS ENGLAND 1-1 (KOJU SIMI GBAA SILE 3-4) 03-07-2018
Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Russia bọ sipele to ṣikeji kangun si aṣekagba

Àwọn wo ló ti lọ sílé?

Awọn ikọ agbabọọlu orilẹ-ede bii Argentina, Portugal, Spain, Denmark, Mexico, Japan. Switzerland ati Colombia ti ko ẹrù wọn pada sile.

Awọn to ku ti won n kopa ninu ipele ṣikeji si àṣekagba ni: Uruguay, France, Brazil, Belgium, Sweden, England, Russia ati Croatia.

Ipele kò-mẹsẹ̀-o-yọ, idije to ṣikeji si aṣekagba lo déé duro bayii ni Russia ti ẹnikẹni to ba ti fidi rẹmi n pada sile.

ÌSÒRÍ ORILẸ-EDE TO KOPA KINI WỌN GBÁ? ỌJỌ WO NI WỌN GBÁ IDIJE WỌN?
IKINI FRANCE VS URUGUAY 0-2 06-07-2018
IKINI BRAZIL VS BELGIUM 1-2 06-07-2018
IKINI SWEDEN VS ENGLAND 0-2 07-07-2018 (AGOGO META OSAN)
IKINI RUSSIA VS CROATIA 2-2 (KOJU SIMI GBAA SILE 4-3) 07-07-2018 (AGOGO MEJE ALE)

Àwọn wo ló ti lọ sílé lẹ́yin ipele ṣikejì?

Orilẹ-ede Uruguay, ati Brazil ti yọ kuro ninu ipele yii nigba ti France ati Belgium ṣíná fún wọn.

Bakan naa ni Sweden ati Russia to n gbalejo idije todun 2018 naa ti ja kuro ninu idije.

Ipele kò-mẹsẹ̀-o-yọ, esi idije to kangun si aṣekagba ni Russia ti awọn to ti fidi rẹmi ti pada sile.

ÌSÒRÍ ORILẸ-EDE TO KOPA KINI WỌN GBÁ? ỌJỌ WO NI WỌN GBÁ IDIJE WỌN?
IKINI FRANCE VS URUGUAY 1-0 10-07-2018
IKINI CROATIA VS ENGLAND 2-1 11-07-2018
Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán England yoo koju Belgium fun ipo keta

Àṣekágbá World Cup 2018

Orilẹ-ede England pada lọ sile lai duro gba ife ẹyẹ ti wọn fẹ gbe lọ sile nigba ti Belgium gbo ewuro si oju wọn pelu ami ayo meji sodo lọjọ Abamẹta.

Image copyright @fifa
Àkọlé àwòrán Wo àwọn agbabọọlu to maa koju ará wọn lọsan yii ni Russia

Oni ni France yoo koju Croatia lati mọ orilẹ-ede ti ife ẹyẹ agbaye n lọ fódun 2018.

ÌSÒRÍ ORILẸ-EDE TO KOPA KINI WỌN GBÁ? ỌJỌ WO NI WỌN GBÁ IDIJE WỌN?
IKINI ENGLAND VS BELGIUM (IPO KETA) 0-2 14-07-2018 (ỌJỌ ABAMẸTA)
IKINI FRANCE VS CROATIA (IPO KINI ATI KEJI) ???? 15-07-2018 (ỌJỌ AIKU)

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÈ gbọ àlàyé lẹnu àwọn ti ójúẹlẹgba leko irú iṣẹ ti oògùn olóró má n ṣé lara.
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÌjà ọlọ́pàá àti alápatà ni Bodija gbẹ̀mí Sulia aláìṣẹ̀ ni UCH
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionPlateau: Àsìkó tó láti fi káádì ìdìbò yanjú ọ̀rọ̀ Buhari
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÀyàn: Ti mo bá ti gbọ́ ohùn ìlù ni àárẹ́ mi ma ń lọ!