Ekiti 2018: Ọlọ́pàá bá àwọn olóṣèlú tó ń fapájánú ṣe ìpàdé àláfíà

Àkọlé àwòrán Ọlọpaa Ekiti ni ki onikaluku lọ so ewé agbéjẹ́ mọ́wọ́

Agbofinro nipinlẹ Ekiti ti ṣe ipade tùbí-ǹ-nùbí pẹlu gbogbo awọn oludije

Wọn ba gbogbo àwọn oludije fun ipo gomina nipinlẹ naa sọrọ lati rii daju pe idibo naa lọ nirọwọ-rọsẹ lai mu ẹmi kankan lọ.Nibi ipade naa to waye ni olu ileeṣẹ ọlọpaa nílu Ado Ekiti Kọmiṣọna ọlọpaa Bello Ahmed, ni awọn Oludije ati awọn aṣoju kọọkan ti fẹnuko lati tẹle ilana alaafia gbogbo ti ofin ti gbe kalẹ lori idibo.Kọmiṣọna Ọlọpaa Ahmed ni ko ni saaye ìrégbè ṣaaju, lasiko ati lẹyin idibo naa fun awọn ọbayejẹ ẹda.

"A ti gbe bi oju ọjọ eto òṣèlú ṣe ri lọwọ nipinlẹ Ekiti yẹ wo, a si rii pe nkan ti fẹ maa mu ọwọ wahala dani. Nibayii a ti waasu fun wọn, won si ti seleri pe ko sewu.Sugbon eyikeyi to ba kuna lati gba alafia laaye ,yoo fi ẹnu fẹra bi abẹbẹ."

Àkọlé àwòrán Ifọwọsowọpọ nikan lo lè jẹ ki eto idibo Ekiti kẹsẹjari
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionIjamba ina Eko; Awakọ ni omi gọta lo yọ oun ninu ijamba ina

Kini ajọ eleto idibo, INEC sọ?Ọga agba ajọ INEC nipinlẹ Ekiti, Ọjọgbọn AbdulGaniyu Raji pẹlu ni eto gbogbo ti to fun idibo ti ko ni lẹja-n-bakan ninu loṣu keje nipinlẹ Ekiti.Ọjọgbọn Raji ṣalaye fawọn oniroyin ninu eyi ti ikọ BBC Yoruba pẹlu wa, pe ireti oun ni pe awọn oludije atawọn ololufẹ wọn yoo gba alaafia laaye."A ti gba idaniloju lọdọ awọn agbofinro lori aabo, awọn oloṣelu naa si ti gba lati fi ewe ọmọ mọ́ awọn èèyàn wọn leti, o di dandan ki eto idibo yii tuba-tuṣẹ."

Awọn oludije kan ṣi n fapa janu.Awọn oludije to ba ikọ BBC Yoruba soro ni ko sewu lẹgbẹrun ẹkọ afi taidun ọbẹ̀ ati pe sẹpẹ ni awọn wa fun idibo naa.Amọṣa, oludije fun ẹgbẹ oṣelu APC, Kayode Fayemi, kọminu lori bi ipaniyan ṣe ti n waye bayii ṣaaju idibo naa.

Fayemi, ti Femi Bamiṣilẹ, ṣoju fun ni o yẹ ki awon agbofinro o wa nkan ṣe si ipaniyan naa."A o fẹ bi ipaniyan ṣe bẹrẹ yii paapaa bi o ṣe jẹ pe àwọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu kan ni awọn olubi ẹda yii n pa. Ki awọn agbofinro o a wa wadi awọn to wa nidi rẹ."Ni tirẹ, igbakeji gomina ipinlẹ Ekiti, Olusola Eleka, to n dije fun PDP ni ṣaaju asiko yii ko si ohun to n da omi alafia ru ni Ekiti ayafi igbati awon 'oloṣelu kan' wọ agbami oselu ipinlẹ naa.

Awon Oludije ẹgbẹ oṣelu AD, Agboọla Ọlaniyi ati APGA, Ajíhìnrere Gbenga Adekunle, kin ọrọ Eleka leyin ti won si ṣalaye pe ko si ipinnu ati du ipo oludije yoowu tó yẹ ko mu emi tabi dukia awọn eeyan ipinlẹ Ekiti lọ.Lara awon ileeṣẹ agbofinro to tun kopa nibi ipade apero naa ni àjọ ọtẹlẹmuyẹ apapọ Naijiria, DSS, ajọ abo ara ẹni laabo ilu, Civil Defence, ileesẹ to n mojuto iwọle-wọde, NIS atawọn ajọ miran.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÀyàn: Ti mo bá ti gbọ́ ohùn ìlù ni àárẹ́ mi ma ń lọ!
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÈ gbọ àlàyé lẹnu àwọn ti ójúẹlẹgba leko irú iṣẹ ti oògùn olóró má n ṣé lara.