#Russia2018: Ronaldo àti Messi dágbére fún ife ẹ̀yẹ àgbáyé

Cristiano Ronaldo àti Lionel Messi Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ronaldo àti Messi kùnà láti gba ife ẹ̀yẹ àgbáyé ọdún yìí ní Russia

Agbaọjẹ agbabọọlu meji l'agbaye, Cristiano Ronaldo ati Lionel Messi dagbere fun idije ife ẹyẹ agbaye to n lọ lọwọ l'orilẹede Russia lọjọ kan naa.

Messi to jẹ balogun ikọ ẹgbẹ agbabọọlu Argentina lo kọkọ kuna lati tẹsiwaju lẹyin ti France fiya jẹ Argentina pẹlu ami ayo mẹrin si mẹta, 4-3.

Ayo meji ọtọọtọ ni ọdọmọde agbabọọlu ilẹ France, Kylian Mbappe gba s'awọn nigbati Messi kuna lati ri kankan gba.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ronaldo naa tẹle Messi jade kuro ninu idije ọhun lẹyin ti Portugal fidi rẹmi ninu ifẹsẹwọnsẹ wọn pẹlu Uruguay pẹlu ami ayo meji si ẹyọkan.

Edison Cavani lo gba ayo mejeeji wọle ti gbogbo igbiyanju Ronaldo ko si le mu ami ayo kankan jade.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ronoldo àti Messi kùnà láti gbáyò s'áwọ̀n nínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ tí wọ́n gbá kẹ́yìn ní Russia

Messi gba ami ayo kan s'awọn ninu ninu idije ife ẹyẹ agbaye ọdun 2018, nigbati Ronaldo gba mẹrin s'awọn.

Ko si ẹni to ti i gba ife ẹyẹ agbaye ri ninu awọn mejeeji.