Salah àti Liverpool buwọlu ìwé àdéhùn ọlọjọ gb'ọrọ

Aworan Mo Salah

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ìlúmọ̀ọ́ká agbábọ́ọ̀lù orílẹ̀èdè Egypt Mohammed Salah ni agbábọ́ọ̀lù ọmọ ilẹ̀ Áfíríkà tó jẹ góòlù tó pọ̀jù ní sáà ìdíje bọ́ọ̀lù kan ní líìgì Premiership.

Mohammed Salah to jẹ gbajugbaja agbaboolu fún ẹgbẹ́ agbaboolu Liverpool ti buwọ́lù ìwé àdéhùn ọlọjọ gb'ọrọ.

Lọ́jọ́ ajé ni ẹgbẹ agbaboolu náà fí ìkéde bibuwọlu ìwé yìí sójú òpó Twitter wọn.

Akọ́nimọ̀ọọ́gba fún ẹgbẹ náà Juergen Klopp bakannna sọ ní ojú òpó ẹgbẹ náà pé ''ìròyìn nlá leyi jẹ́ fún wà o sí jẹ ọnà àti ṣe ìwúrí fún ẹni tó kópa ríbiríbi fún ìdàgbàsókè ẹgbẹ́ wà.''

Klopp ni ''nkán meji ni eyi tọka sí: ìgbàgbọ rẹ nínú ẹgbẹ agbabọ́ọ̀lu wa ati ìgbàgbọ wa nínú rẹ''

Ìgbà mẹtalelogun ni Mo Salah gbà bọ́ọ̀lù wọnú awọn fún ẹgbẹ Liverpool nínú ifẹsẹwọnsẹ mejilelọgbọn ní sáà bóòlù Premiership ọdún 2017/2018.

Ìgbìyànjú rẹ̀ ṣé òkùnfà bi Liverpool ṣé gba ipò kẹrin lórí afárá líìgì Premiership ọdún yii.