#Russia2018: Brazil wọ ìpele kẹta nínú ife ẹ̀yẹ àgbáyé

Neymar Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Neymar gbá bọ́ọ̀lù sáwọ̀n nínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ láàrin Brazil àti Mexico

Orilẹede Brazil pegede fun ipele ''quarter finals'' ninu idije ife ẹyẹ agbaye to n lọ lọwọ l'orilẹede Russia.

Ẹlẹsẹ-ayo Neymar ati Firmino lo gba bọọlu s'awọn bi Brazil ti jawe olubori pẹlu ami ayo meji sodo.

Iṣẹju mọkanlelaadọta ni Neymar kọkọ gba bọọlu sawọn ki Firmino to fi kan si nigbati o ku iṣẹju meji ki ifẹsẹwọnsẹ naa pari.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Brazil yoo koju ẹni to ba jawe olubori laarin Belgium ati Japan.

Igba keje re e ti Mexico yoo degbere fun idije ife ẹyẹ agbaye ni ipele keji.