#Russia2018: Ologbo to sọ asọtẹlẹ Super eagles ati Argentina ti ku

Aworan Ologbo kan Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ki o to jade laye, ifẹsẹwọnsẹ mẹfa ọtọọtọ ni olonginni naa sọ asọtẹlẹ nipa wọn

Baidian'er, ologbo to di olokiki pẹlu awọn asọtẹlẹ to sọ lori awọn ikọ ti yoo bori tabi ja kulẹ ninu idije ife ẹyẹ agbaye, Russia 2018 ti jade laye.

Ile iko nkan iṣẹmbaye si lorilẹede China ti kọkọ kede rẹ pe aarẹ mu ologinni yii, ki o to di pe o ba ọlọjọ lọ.

Ki o to jade laye, ifẹsẹwọnsẹ mẹfa ọtọọtọ ni olonginni naa sọ asọtẹlẹ nipa wọn, gbogbo rẹ lo si ṣẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ologbo ti ko nile ni Baidian'er lagbegbe ibudo ikonkan iṣẹmbaye si aafin si ni ilu Beijing ki wọn to gbe abọ ounjẹ meji pẹlu aṣia orilẹede mejoi to n koju ara wọn si iwaju rẹ, eyi ti o ba jẹ lo si n gbegba oroke.

Amọṣa, asọtẹlẹ rẹ lori ifẹsẹwọnsẹ laarin orilẹede Argentina ati Nigeria ni asọgbẹyin rẹ.

Baidian'er sọ asọtẹlẹ pe Super eagles yoo fidirẹmi, bẹẹ lo si ri.