Russia 2018: England ti bọ́ sí ìpele tó kángun sí àṣekágbá

Dele Alli

Oríṣun àwòrán, @dele_official

Àkọlé àwòrán,

Idije to kan fun England ni lati wọ̀yá ija pẹlu Russia tabi Croatia

Orilede England ti bọ si ipele to kangun si aṣekagba ninu idije ife agbaye fun igba akọkọ lati ọdun 1990.

Ọpẹlọpẹ ipa takun-takun ti Harry Maguire ati Dele Alli ko ninu idije naa to waye laarin wọn ati Sweden, pẹlu bi awọn mejeeji ṣe fi ori gba bọọlu wọle sinu àwọ̀n alatako wọn, Sweden.

Idije to kan fun England ni lati wọ̀yá ija pẹlu Russia tabi Croatia l'Ọ̀jọ́rú to n bọ ni papa iṣere Luzhniki to n bẹ ni ìlú Russia, nibi ti wọn yoo ti ja fita-fita lati mọ ẹni ti yoo kopa ninu aṣekagba idije Russia 2018 ti yoo waye lọjọ kẹẹdogun, oṣu yii.

Orilẹede England yoo mọ ikọ ti wọn o koju ni ipele to kangun si aṣekagba lẹyin ifiga-gbaga laarin Russia ati Croatia ti yoo waye laago meje alẹ Àbámẹ́ta.