#Russia 2018: Belgium kojú France n'ìpele ''semi finals''

Antoine Griezmann, Romelu Lukaku, Kylian Mbappe àti Eden Hazard Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Pẹ́pẹ́pẹ yóò pọmọ bí France ti kojú Belgium nínu ìdíje ife ẹ̀yẹ àgbáyé ní Russia

Ikọ agbabọọlu Belgium yoo waako pẹlu ikọ Faranse lọjọ ìṣẹgun ninu ifẹsẹwọnsẹ to kangun si aṣekagba ninu idije ife ẹyẹ agbaye to n lọ lọwọ l'orilẹede Russia.

Ikọ Belgium ti wọn jẹ ẹgbẹ agbabọọlu to gbayo s'awọn julọ ninu idije naa ti ni ami ayo mẹrinla ninu ifẹsẹwọnsẹ marun-un ti wọn ti gba.

Belgium fakọyọ lẹyin ti wọn sin ikọ Brazil to ti gba ife ẹyẹ agbaye lẹẹmarun-un ọtọtọtọ lọ'le lati Russia pẹlu ami ayo 2-1 ni ipele ''quarter finals.''

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionCUPP: JJ Ọmọjuwa sọ ohun tí ìdàpọ̀ àwọn ẹgbẹ́ yìí yóò jẹ́

Orilẹede Faranse naa fagba han ẹgbẹ agbabọọlu Uruguay pẹlu ami ayo meji sodo ki wọn to pegede fun ipele to kangun si aṣekagba.

Ifẹsẹwọnsẹ to kangun si aṣekagba keji laarin ẹgbẹ agbabọọlu England ati Croatia ti yoo waye l'Ọjọru.