#Russia 2018: Ta ni yóò gba ''golden boot'' ní Russia?

Harry Kane Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Harry Kane ni ọ̀pọ̀ olólùfẹ́ eré bọ́ọ̀lù lérò pé yóò ''Golden Boot'' ní Russia

Idije fun agbabọọlu ti yoo gba ami ẹyẹ fun ẹni to gba bọọlu sawọn ju ''Golden Boot'' ninu idije ife ẹyẹ agbaye ti gbona sii bayii bi idije naa ti wọ ipele to kangun si aṣekagba.

Ọgọ́jọ ayo o din mẹta ni awọn agbabọọlu ti gba sawọn ninu ifẹsẹwọnsẹ ọgọta ti wọn gba lati igba ti idije naa ti bẹ̀rẹ̀.

Ẹlẹsẹ ayo to jẹ ọmọbibi ilẹ Gẹẹsi Harry Kane lo n siwaju ninu awọn ti wọn gba bọọlu sawọn ju ni Russia pẹlu ami ayo mẹfa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Kane yoo ni anfani lati fi kun ami ayo rẹ nigba ti ilẹ Gẹẹsi ba koju Croatia ninu ifẹsẹwọnsẹ to kangun si aṣekagba wọn l'Ọjọru.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sí dé ìpele tó kángun sí àṣekágbá nínú ìdíje ife ẹ̀yẹ àgbáyé fún ìgbà àkọ́kọ́ ní ọdún méjìdínlọ́gbọ̀n

Agbaọjẹ agbabọọlu Cristiano Ronaldo to jẹ ọmọbibi orilẹede Portugal gba ayo mẹrin sawọn ki orilẹede naa to lọ'le lati Russia.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Cristiano Ronaldo wá lára àwọn àgbàọ̀jẹ̀ agbábọ́ọ̀lù tí kò gba ife ẹ̀yẹ àgbáyé rí

Ẹlẹsẹ ayo Romelu Lukaku to n gba bọọlu fun Belgium naa ti gba ayo mẹrin sawọn, o si ni anfani lati fikun ami ayo rẹ nigbati Belgium ba koju France.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ikọ̀ Belgium fakọyọ nígbàtí lé Brazil lọ'lé láti Russia

Ọmọ ilẹ Russia ti wọn n gbalejo idije ife ẹyẹ agbaye Denis Cheryshev naa wa lara awọn to ti gb'ayo mẹrin sawọn ni Russia.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Orílẹ́èdè Russia gbìyànjú ṣùgbọ́n wan kùnà láti kọjá ìpele ''quarter finals'' nínú ife ẹ̀yẹ àgbáyé

Antoine Griezmann to jẹ agbabọọlu iwaju fun orilẹede France naa ko gbẹyin ninu awọn ẹlẹsẹ ayo lẹyin ti o ti gb'ayo mẹta wọle.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ọdún 1998 ni ikọ̀ France ti gba ife ẹ̀yẹ àgbáyé kẹ́yìn

Kylian Mbappe ti oun naa jẹ ọmọbibi ilẹ France ni ami ayo mẹta ninu idije ife ẹyẹ agbaye to n lọ.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Kylian Mbappe fakọyọ nínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ láàrin France àti Uruguay

Diego Costa ti o ti d'ero ile bayi pẹlu ẹgbẹ agbabọọlu Spain naa gb'ayo mẹta sawọn ki wọn to l'ọle lati Russia.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ọmọbíbí orílẹ́èdè Brazil ni Diego Costa ṣùgbọ́n ó pinu láti máa ṣojú ilẹ̀ Spain