World Cup 2018: France fàgbà hàn Croatia pẹ̀lú àmì ayò 4-2

Ikọ agbabọọlu France
Àkọlé àwòrán,

Ìgbà kejì nìyí tí France yóò gba ife ẹ̀yẹ àgbáyé

France ló gbé ife ẹ̀yẹ àgbáyé tọdún 2018 lọ!

Orilẹ-ede mẹtalelọgbọn lo bẹrẹ idije Russia 2018 pe ki ife ẹyẹ agbaye lè tẹle wọn lọ sile ṣugbọn France lo gbaa lọ bayii bi wọn ṣe na Croatia sipo keji ti Belgium si gba ipo kẹta.

Modric ti orilẹ-ede Croatia lo gba ami ẹyẹ ẹlẹsẹ ayo (Golden Boot) fun todun 2018.

Idije àṣekágbá Russia 2018

Croatia ati France ni wọn jọ waako lati mọ ẹni ti yoo gba ife ẹyẹ lọ.

Ami ayo ookan si ookan ni wọn jọ wa ti ikọ agbabọọlu mejeeji n tiraka ki rẹfiri to ni ki France gba kọju-simi-n-gbaa sile lataari pe ọwọ ọmọ Croatia kan bọọlu.

Subasic ilẹ̀ Croatia kò rí bọ́ọ̀lù kọjú-sími-n-gbaá sílé naa mú ni ayò bá di 2-1.

Àkọlé àwòrán,

Antoine Griezmann lo gbá bọọlu kọju-simi-n-gbaa sile fun àwọn Les Bleus.

Paul Pogba náà bá tun fọba lee fun wọn, ni France ati Croatia jọ n waako lori papa fun idije aṣekagba Russia 2018 ti oju gbogbo wa lara wọn.

Àkọlé àwòrán,

Paul Pogba ba France fọba lee, o ṣeeṣe ki ife ẹyẹ lọ France ti Croatia kò ba ṣọra

Lọwọlọwọ ayò ti di mẹrin si meji bi France ṣe n fagba han Croatia pe, a ju ara wa lọ.

Àkọlé àwòrán,

Amule France kawọmọri nigba to ṣe aṣiṣe to sọ idije pẹlu Croatia di 4-2

Ko pẹ ni Croatia jẹ ikeji lataari aṣiṣe France. Mario Mandzukic jere lara aṣiṣe Lloris layo ba di 4-2.

Ami ayo mẹrin si meji yii ni wọn jọ gba de opin ti idije ife ẹyẹ agbye 2018 fi wa sopin ti gbogbo e tun di 2022.

Orile-ede Qatar ni yoo gbalejo ife ẹye agbaye lodun 2022.

Latẹyinwa

Igba akọkọ ni yi ti France yoo de ipele aṣekagba idije ife ẹyẹ FIFA lati ọdun 2006.

Orilẹ-ede France ti kogoja lati kopa ni ipele aṣekagba idije ife ẹyẹ agbaye FIFA to n lọ lọwọ lorilẹede Russia.

Orilẹ-ede France fi agba han orilẹ-ede Belgium pẹlu ami ayo kan si odo.

Àkọlé àwòrán,

Samuel Umtiti lo fi ori kan bọọlu wọ awọn Belgium eleyi to fun France lanfani ipele aṣekagba

Ifẹsẹwọnsẹ ọhun jẹwọ ara rẹ gẹgẹ bii ifigagbaga laarin awọn ikọ akọni agbabọọlu meji ni ibamu pẹlu ireti awọn onwoye ati ololufẹ ere bọọlu jakejado agbaye.

Àkọlé àwòrán,

Eyi ni igba akọkọ ti orilẹede France yoo de ipele aṣekagba idije ife ẹyẹ FIFA lati ọdun 2006

Aarẹ orilẹede France, Ọgbẹni Emmanuel Macron ati Alayeluwa ọba Philippe ti orilẹede Belgium wa nikalẹ lati yẹ awọn agbabọọlu orilẹede wọn si.

Eyi ni igba akọkọ ti orilẹede France yoo de ipele aṣekagba idije ife ẹyẹ FIFA lati ọdun 2006 ti wọn ti fidirẹmi nigba ti wọn koju ikọ orilẹede Italy.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Eyi si ni igba akọkọ ti orilẹede france ati Belgium yoo forigbari ni idije ife ẹyẹ agbaye lati ọdun mejilelọgbọn sẹyin ti wọn ti pade ni idije ife ẹyẹ agbaye to waye lorilẹede Mexico lọdun 1986.

Samuel Umtiti, agbabọọlu ọwọ ẹyin lo fi ori kan bọọlu wọ awọn Belgium eleyi to fun wọn lanfani lati tẹsiwaju si ipele aṣekagba.