#Russia2018: Southgate ní ìdánwò ńlá ni Croatia fún England

Àwọn agbábọ́ọ̀lù ikọ̀ England àti Croatia Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ikọ̀ England àti Croatia kojí ara wọn nilu Moscow

Bi ẹgbẹ agbabọọlu England ti ṣetan lati koju Croatia ninu ifẹsẹwọnsẹ to kangun si aṣekagba ninu idije ife ẹyẹ agbaye, akọnimọọgba wọn Gareth Southgate sọ pe ikọ Croatia jẹ idanwo to le ju fun England ninu idije naa.

Ẹgbẹ agbabọọlu England jawe olubori ninu ifẹwọnsẹ wọn pẹlu Tunisia, Panama, Sweden ati Colombia, ṣugbọn wọn fidi rẹmi nigbati wọn koju Belgium.

Akọnimọọgba Southgate gbedi fun awọn agbaọjẹ agbabọọlu fun orilẹede Croatia bii Luka Modric, Ivan Rakitic ati Mario Mandzukic to jẹ ẹlẹsẹ ayo wọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Eleyi ni igba akọkọ ti England yoo wọ ipele to kangun si aṣekagba ninu idije ife ẹyẹ agbaye lati ọdun 1990.

Ikọ to ba jawe olubori ninu England ati Croatia ni yoo koju France ninu ifẹsẹwọnsẹ aṣekagba lọjọ Aiku.