Europa League: Chelsea wọ ìpele ẹlẹ́ni-méjìlélọ́gbọ̀n

Àwọn agbábọ́ọ̀lù Chelsea

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Chelsea pegede ninu idije Europa

Ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea ti wọn ipele ẹlẹni-mejilelọgbọn bayii lẹyin ti wọn ikọ Bate Borisov mọle pẹlu ami ayokan sodo ninu idije Europa lalẹ Ọjọbọ lorilẹede Belarus.

Ẹlẹsẹ ayo Olivier Giroud lo gbayo naa wọle.

Ikọ Chelsea to ti n fakọyọ lati igba ti akọnimọọgba wọn tuntun Maurizio Sarri ti de ni ibẹrẹ saa yii, ko tii fidi rẹmi ninu ifẹsẹwọnsẹ kankan ni saa yii.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Ìnú mi kìí dùn nígbà trí mo ń ṣiṣẹ́ ni bánkì tó ìgbà ti mo bẹ̀rẹ̀ mẹkáníìkì

Akọnimọọgba Sarri ko mu awọn agbabọọlu bi Alvaro Morata, David Luiz, Antonio Rudiger ati Marcos Alonso rinrin ajo lọ fun ifẹsẹwọnsẹ ọhun.

Ṣugbọn ẹlẹsẹ-ayo Eden Hazard wa lara awọn ti yoo koju Bate Borisov.

Chelsea le Conte lọ

Ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea ti kede lori opo Twitter pe wọn ti da akọnimọọgba Antonio Conte duro lẹnu iṣẹ.

Ikọ Chelsea sọrọ lori opo Twitter pe awọn koni ohunkohun ṣe mọ pẹlu Conte mọ lẹyin ọdun meji to ti lo pẹlu ikọ agbabọọlu naa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Chelsea pínyà pẹ̀lú akọ́nimọ̀ọ́gbá Antonio Conte

Lakoko rẹ ni Chelsea, Conte gbe ife ẹyẹ Premier League ati FA pẹlu ẹgbẹ agbabọọlu to wa ni ilu London.

Awọn alakoso Chelsea fi adura sin Conte bi o ti fi ẹgbẹ agbabọọlu naa silẹ.