Russia2018: àwọn àsìkò mọ́legbàgbé nínú ìdíje ife ẹ̀yẹ àgbáyé

Nestor Pitana Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Rẹfirí Nestor Pitana ló darí ifẹsẹ̀wọnsẹ̀ àṣekágbá láàrin France àti Croatia

Idije ife ẹyẹ agbaye 2018 World Cup ti orilẹ-ede Russia gbalejo rẹ ti pari, ṣugbọn o kun fun awọn asiko mọlegbagbe.

Diẹ lara awọn asiko mọlegbagbe ọhn nigba ti idije naa n lọ lọwọ niyii.

Ninu ojo ni awọn agbabọọlu France ti gba ife ẹyẹ naa lẹyin ti wọn na ikọ Croatia pẹlu ami ayo 4-2 ninu ifẹsẹwọnsẹ aṣekagba idije naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÈdè Ekiti ni wọ́n fi kí Fayẹmi kú oríire

Ninu wẹliwẹli òjò ni awọn agbabọọlu France ti sẹ ajọyọ ife ẹyẹ agbaye gba nile Moscow lọjọ Aiku.

Awọn agbabọọlu naa ko wo ti ojo rara, nṣe ni wọn yọ ti wọn si n jo pẹlu ife ẹyẹ naa lọwọ wọn.

Rẹfirí Nestor Pitana to jẹ ọmọbibi orilẹede Argentina ti di ilumọọka lẹyin to fun France ''penalty'' ninu ifẹsẹwọnsẹ aṣekagba idije ife ẹyẹ agba ni Russia.

Ọpọ eeyan lo ro pe Pitana fi igba kan bọkan ninu lẹyin ti o fun France ni ''penalty'' naa ti France si bẹrẹ si ṣiwaaju pẹlu ami ayo 2-1.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Rẹfirí Nestor Pitana ló darí ifẹsẹ̀wọnsẹ̀ àṣekágbá láàrin France àti Croatia

Agbaọjẹ agbabọọlu Luka Modric to jẹ balogun ẹgbẹ agbabọọlu Croatia lo gba ami ẹyẹ agbabọọlu to pegede julọ ninu idije ife ẹyẹ agbaye.

Bakannaa, Kylian Mbappe to jẹ ọmọ ọdun mọkandinlogun lo gba ami ẹyẹ ọdọmọde agbabọọlu to pegede julọ ninu idije ife ẹyẹ agbaye ni Russia.

Agbaọjẹ agbabọọlu meji lagbaye Cristiano Ronaldo ati Lionel Messi lọle lati Russia lọjọ kan naa.

Messi dagbere fun Russia lẹyin ti orilẹede rẹ Argentina fidi rẹmi ninu ifẹsẹwọnsẹ ipele keji wọn pẹlu ikọ France.

Ronaldo naa tẹle Messi lọọle lẹyin ti Uruguay fiya jẹorilẹede rẹ Portugal.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ọjọ́ kannáà ni Lionel Messi àti Cristiano Ronaldo fi ìdíje ife ẹ̀yẹ àgbáyé sílẹ̀