Mesut Ozil fi ikọ̀ Germany sílẹ̀ lórí ẹ̀sùn ẹlẹ́yàmẹ̀yà

Mesut Ozil Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Mesut Ozil fi ikọ̀ Germany sílẹ̀

Agbabọọlu ikọ Arsenal to jẹ ọmọbibi orilẹede Germany, Mesut Ozil sọ pe, oun ko ni ṣoju orilẹede naa mọ ninu idije ere bọọlu.

Ozil gbe igbesẹ naa lẹyin to f'ẹsun ẹleyamẹya kan awọn oṣiṣẹ ajọ to n ri si ere bọọlu l'orilẹede naa.

Ozil wa lara awọn agbabọọlu to ṣoju Germany ninu idije ife ẹyẹ ni Russia nibi ti wọn ti fidi rẹmi.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionBọlanle Aliyu: N kò nílò bàbá ìsàlẹ̀ láti di gómìnà

Ọpọ lo di ẹbi aifakọkọyọ ikọ Germany ninu idije naa ru Ozil, eleyi to ba ninu jẹ.

Fọto ti Ozil ya pẹlu Aarẹ orilẹede Turkey Tayyip Erdogan ṣaaju idije ife ẹyẹ Agbaye lo mu ki ọpọ ọmọ Germany doju kọ pe ko ni otitọ si ilẹ Germany.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Mesut Ozil jẹ́ ọ̀kan lára àwọn agbábọ́ọ̀lù tó gba ife ẹ̀yẹ àgbáyé fún orílẹ́èdè Germany ní ọdún 2014

Lootọ ni wọn bi Ozil si orilẹede Germany ṣugbọn lati orilẹede Turkey ni awọn obi rẹ ti wa.

Ozil sọrọ lori opo Twitter rẹ pe oun roo daradara ki oun to gbe igbesẹ naa lati fi ẹgbẹ agbabọọlu Germany silẹ.