NFF: Ìwáàdí ti bẹ̀rẹ̀ lórí ẹ̀sun rìbá tí wọ́n fi kan Salisu Yusuf

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ileeṣẹ BBC lo gbe iroyin kan jade pe olukọni ikọ Super eagles naa gba owo riba lati yan agbabọọlu si ikọ rẹ

Ajọ ere bọọlu afẹsẹgba lorilẹede Naijiria, NFF ti bẹrẹ iwadii lori ẹsun owo riba gbigba ti wọn fi kan olukọni ikọ agbabọọlu Super Eagles, Salisu Yusuf.

Gẹgẹ bii iroyin to fi si ori ikanni ayelujara twitter rẹ, ajọ NFF ni awọn ti kẹẹfin iroyin kan lawọn ileeṣẹ iroyin lorilẹede naijiria lẹyin ti ileeṣẹ BBC ti gbe akanṣe fidio iwadi kan jade lori olukọni agba fun ikọ agbabọọlu Super eagles ti wọn fẹsun kan pe o gba owo riba.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

"Ni bayii, ajọ NFF ti bẹrẹ iwadi lori ọrọ naa lati se iranwọ to yẹ fun igbimọ to n risi iwa ọmọluabi ati ẹtọ lajọ naa.

Ọgbẹni Yusuf to jẹ igbakeji fun olukọni Gernot Rohr lọ si idije ife ẹyẹ agbaye to ṣẹ pari laipẹ yii lorilẹede Russia ti faake kọri pe ohun ko jẹbi iwa ibajẹ kankan lori iṣẹlẹ naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÌwádìí Anas: $1000 ni rìbá tí akọ́ni-mọ̀ọ́gbá Super Eagles gba

O ni ẹbun lasan ni owo naa ati pe awọn agbabọọlu ti oun mu fun idije nigba ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ pegede ki oun to lee mu wọn.

Bakan naa lawọn akẹgbẹ Yusuf ni ẹgbẹ awọn olukọni ere bọọlu afẹsẹgba lorilẹede Naijiria ti gbaruku ti olukọni ikọ Super eagles naa.