Ìbò NFF: Ìbò 34 ni Pinnick fi borí àwọn olùdíje yòkúù

An eeyan n dunnu pe Pinnicks le alaga

Oríṣun àwòrán, @thenff

Alaga fun ajọ elere bọọlu lorilẹ́-ede Naijiria (NFF), Amaju Pinnick ni wọn tun ti dibo yan pada lọsan ọjọbọ gẹgẹ bii alaga ajọ naa.

Iroyin kan ti ajọ NFF fi si oju opo Tweeter rẹ lo kede bẹẹ pẹlu afikun pe ibo mẹrinlelọgbọn ni Pinnick ni, lati bori awọn oludije mẹta yoku, to si gba ipo rẹ pada.

Iroyin naa ni Alhaji Aminu Magari lo se ipo keji pẹlu ibo mẹjọ, nigba ti Taiwo Ogunjọbi ni ibo meji, ti Chinedu Okoye ko si ni ibo kankan.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Onigbinde àti Owolabi: Ààrẹ NFF tuntun gbọdọ̀ sàwárí ọ̀jẹ̀ wẹ́wẹ́ agbábọ́ọ́lù

Awọn asoju mẹrinlelogoji la gbọ pe wọn wa lati awọn ipinlẹ gbogbo to wa lorilẹ-ede yii, pẹlu awọn ajọ miran, bii ajọ awọn adari ere bọọlu, ẹgbẹ awọn to n se akoso ere bọọlu lori papa ati ẹgbẹ awọn agbabọọlu gbogbo wọn ni wọn si kopa ninu eto idibo naa, to waye ni ipinlẹ Katsina.

Oríṣun àwòrán, @thenff

Alaga igbimọ to n se kokari eto idibo NFF naa, Muhammed Katu lo kede esi ibo ọhun.

Idije Asaba 2018 bẹ̀rẹ

Awọn kan lara awọn elere idaraya to fẹ kopa ninu idije ere idaraya laarin awọn orilẹ-ede nilẹ Afrika, All African Games, to n bẹrẹ ni ilu Asaba, ti se olu ilu ipinlẹ Delta, l'ẹkun aarin gbun-gbun Guusu Naijiria, ni ko ti i gunlẹ si ibi ti idije naa yoo ti waye, lai fi ti idije naa to yẹ ko bẹrẹ lọjọru ṣe.

Akọroyin ere idaraya fun BBC, Janine Anthony, to wa ni papa iṣere ti idije naa yoo ti waye jabọ pe, awọn elere idaraya to n ṣoju orilẹede South Africa ati Botswana ti gunlẹ silu Asaba, ti awọn akẹgbẹ wọn lati Egypt ati Kenya si gunlẹ ni owurọ ọjọ Ọjọru.

Awọn alamojuto idije naa ṣi n reti awọn olukopa lati orilẹede bi Congo ati Burkina Faso.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Ìbaàrún pe ọdún kan

Isoro kan gboogi to n fa idaduro nibi idije naa ni pe, papakọ ofurufu ti wọn fẹ balẹ si kere, eyi to mu ko ṣoro fun awọn baalu nla lati balẹ si bẹ. Eyi lo ti wa mu ki awọn elere idaraya naa maa lo awọn baalu kekeeke to nko wọn wọ Naijiria diẹ-diẹ.

Ni bayi, papa iṣere ti idije naa yoo ti waye ti wa ni ṣiṣi fun igbaradi, sugbọn awọn elere idaraya lati orilẹede Botswana n fi ẹsun kan pe, awọn ko ri ounjẹ to dara fun ilera awọn jẹ.

Ṣaaju ni iroyin gbe e pe, awọn elere idaraya lati Kenya, Eritrea, ati Burkina Faso, to gunlẹ si papakọ Murtala Mohammed to wa nilu Eko, ko ti i raye kuro nibẹ lati bi ọjọ melo kan nitori awọn kudiẹ-kudiẹ.

Oríṣun àwòrán, Abdinoor Aden

Àkọlé àwòrán,

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn eléré ìdárayá ní kò tí ì rí ààyè kúró ní pápákọ̀ òfurufú láti bí ọjọ méjì

Bi o tilẹ jẹ wipe, igbimọ to n mojuto idije naa ni Naijiria, to fi mọ gomina ipinlẹ Delata to n gbalejo idije naa, Ifeanyi Okowa, ni gbogbo eto lo ti to fun idije naa lati jẹ ko yọri sirere, sibẹ, ero awọn elere idaraya ati awọn alamojuto to wa lati orilẹede mi i yatọ si ti wọn.

Akọnimọọgba fun ikọ orilẹede Bulgeria, Benid Amar, ni oun fi oju ri i bi awọn elere idaraya kan ṣe koju wahala ni papakọ ọkọ ofurufu ilu Eko fun ọjọ meji.

O ni idije ti 2018 yii, ni amojuto rẹ ko dara rara lati igba ti oun ti n kopa ninu iru idije bẹẹ.

Lori awọn kudiẹ-kudiẹ yii, gbajugbaja elere idaraya commonwealth, to tun jẹ ọmọ Naijiria, Blessing Okagbare, ni nkan ko deede ri bẹẹ.

O ni eyi waye nitori pe igba akọkọ niyi ti Naijiria yoo gbalejo idije naa.

Ati pe awọn ohun to ṣẹlẹ yii jẹ ẹkọ fun awọn ti ọrọ kan.