Ahmed Musa: Musa dèrò Saudi Arabia láti Leicester City

Ahmed Musa Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ahmed Musa ṣe bẹ́ẹ̀ ó fi Premier League sílẹ̀ lọ sí Saudi Arabia

Ẹlẹsẹ ayo ọmọ Naijiria Ahmed Musa ti darapọ mọ ikọ agbabọọlu Al-Nassr ni orilẹede Saudi Arabia.

Ẹgbẹ agbabọọlu Al-Nassr ra Musa lati ikọ agbabọọlu ilẹ Gẹẹsi Leicester City fun £17.5M.

Ẹ o ranti pe Leicester City ra Musa lati ẹgbẹ agbabọọlu CSKA Moscow lọdun 2016 fun £16m.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ sí:

Ṣugbọn wọn da a pada si CSKA Moscow ni saa bọọlu to kọja lẹyin to gbayo meji pere sawọn ninu ifẹsẹwọnsẹ mọkanlelogun.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ahmed Musa gb's bọ́ọ̀lù méjì sáwọ̀n fún Nàìjírìa nínú ìdíje ife ẹ̀yẹ àgbáyé lorílẹ́èdè Russia

Musa ṣoju orilẹede Naijiria ninu ife ẹyẹ agbaye lorilẹede Russia nibi to ti gba ayo meji sawọn ninu ifẹsẹwọnsẹ Naijiria pẹlu Iceland.