2018 FIFA U-20: Falconets Nàìjíríà kúrò ni France padà wálé

Agbábọ́ọ̀lù Falconets ń sọkún

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Nàìjírìa ti ń bọ̀ wálé láti ìdíje FIFA Under 20 World Cup nílẹ̀ Faranse lẹ́yìn tí wọ́n kùnà láti tẹ̀síwájú

Awọn agbabọọlu Niajiria bu sẹkun lẹyin ti ikọ agbabọọlu Spain le wọn lọ le ninu idije FIFA Under 20 World Cup lorilẹ-ede France.

Ami ayo meji sẹyọkan ni Spain fi fagba han wọn ninu ifẹsẹwọnsẹ ọhun ni ipele komẹsẹ-ọ-yọ onikọmẹjọ (quarter finals).

Spain yoo koju ẹgbẹ agbabọọlu orilẹ-ede Faranse nipele to kangun si aṣekagba ninu idije naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Ronke Oṣodi: òótọ́ ọ̀rọ̀ máa ń korò gan ni f'áwa èèyàn

Ikọ agbabọọlu Spain lo kọkọ gbayo meji wọle Naijiria, awọn agbabọọlu Naijiria naa ta biọbiọ lẹyin ti wọn da ayo kan pada.

Ṣugbọn igbiyanju ko to o lẹyin ti Spain yọ wọn ninu idije naa ti wọn si ti dero ile bayii.

Ikọ Falconets ti wọ ipele aṣekagba FIFA Under 20 World Cup lẹẹmeji otọọtọ ṣugbọn wọn kuna lati gba ife ẹyẹ naa.

Kin ni àwọn ohun to yẹ ki o mọ nipa idije naa?

  • Ọdun 2002 ni idije naa bẹrẹ.
  • Orilẹ-ede Germany ati USA lo ti jawe olubori julọ, lẹẹmẹta ẹnikọọkan wọn.
  • Orile-ede Canada lo gbalejo idije akọkọ, sugbọn USA lo gba ife ẹyẹ naa l'ọdun 2002.
  • Ọdun meji-meji ni idije naa maa n waye. Ọdun 2002 lo si bẹrẹ.
  • Idije ti 2018 n waye laarin ọjọ karun un si ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹjọ.

Bi wọn ṣe gba ife ẹyẹ si lati ibẹrẹ

Aaya ti bẹ silẹ ninu idije naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Ọmọ Yoruba ni mi